Yorùbá Àti Ẹwà Rẹ̀

Àwọn ìran Yorùbá ni wọn wà ní apá ìwọ oòrun Nàìjíríà, Benin Republic, apá kan Togo àti Ghana, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n wà káàkiri oríṣìíríṣìí orílẹ̀ èdè ní àgbáyé. Wọ́n dáńtọ́ nínú iṣẹ́ ọnà ṣíṣẹ ní onírúurú ọ̀nà. Lára àwọn iṣẹ́ ọnà wọn ni, oníṣọ̀nà igi àti igbá; amọ̀kòkò, arọ́dẹ àti afayọdárà àti àwọn afirindárà; alágbẹ̀dẹ́; mọlémọlé àti àwọn iṣẹ́ mìíràn tía fi amọ̀ ṣe (lóde òní àwọn ayàwòrán ilé oní sánmọ́ńtì)- kí a tó wá sọ ti àwọn ahunṣọ àti àwọn tí wọ́n ń pa oríṣìíríṣìí aṣọ láró. Ní àfikún, àwọn aránsọ ìgbàlódé, adáṣọlárà, onídìrí àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n fi àrà àti ẹwà kún ìgbé ayé ọmọnìyàn.



Oríṣìíríṣìí àríyàjiyàn ńlá ni ó wà lórí ìtúnmọ “iṣẹ́-ọnà”. Il̀ò ọ̀rọ̀ yí máa ń ṣinilọ́nà bákan nínú gbogbo àṣà àgbáyé, pàápàá jùlọ ní Áfíríkà. Ohun tí a pè ní iṣẹ́ ọnà gẹ́gẹ́ bí oríkí tí àwọn Yúróòpù fún un, ó túnmọ̀ sí ohun tí a ṣẹ̀dá tí a sì yà sọ́tọ̀ fún wíwò nìkan, èyí kò bá ilẹ̀ Áfíríkà mú rárá. Iṣẹ́ ọnà ní Áfíríkà pàápàá ní ilẹ̀ Yorùbá dà bí àrokò ní ìlò àti ní ìṣàfihàn ìpele tí ó wà ní àwùjọ àti agbègbè.

 

Ẹwà iṣẹ́ ọnà fi ara pé èrò nípa imọlára tí ó ní ṣe pẹ̀lú ohun tí ènìyàn ní tàbih ohun tí odíbọ́n pé òun ń ìmọlárà ẹwà. Àwùjọ Yorùbá jẹ́ èyí tí ó ní ètò púpọ̀, ní ti ìpele-ìpele tí ó sì máa ń ṣe okùnfà ìdọ́gba àti ètò. Ìdọ́gba àti ètò jẹ́ èso àwọn ọ̀rọ̀, gbólóhùn, èdè ìperí, àti àkànlò èdè kọ̀ọ̀kan ní inú èdè. 


Fún ìdí èyí, ṣíṣe àgbéyẹ̀wò iṣẹ́ ọnà Yorùbá, jẹ́ ṣiṣe àgbéyẹ̀wò àkóónú àti àkópọ̀ èdè tí ó ní ìtunmọ̀ ní èyí tí àkànlò-èdè, àlọ́, ìtàn àlọ́, ìtàn orírun, ẹ̀sìn àti ìgbàgbọ́, ètò àwùjọ - orírun.

 

A wòye pé ohun tí ó ń jẹ iṣẹ́ ọnà, ni a rí mú jáde láti ara ohun àìrídìmú tí í ṣe “ìṣẹ̀dá ọ̀rọ̀”, èyí tí ó kọ́kọ́ ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá (ẹni tí ó ni ọ̀run) tàbí Elédùmarè ( ẹni tí ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá ní inú ìgbàgbọ́ Yorùbá) ẹni tí ó dá ọ̀rọ̀. 


Rowland Abiodun sọ pé “iṣẹ́-ọnà àti èdè Yorùbá” máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi orísun ìmọ̀ àti ọgbọ́n fún àwọn onímọ̀ àti gbogbo àwùjọ (pàápàá àwọn ènìyàn tí wọ́n máa ń lọ́ sí ilé àkójọpọ̀ ohun ìṣúra ìgbanì). Àwọn ìdojúkọ ọlọ́kòjọ̀kan ni ó wà nínú èyí àti àwọn ohun tí ó lérò nínú iṣẹ́ akadá. 


Ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ọnà ní àwùjọ Yorùbá ní ìtunmọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ sí ìsàlẹ̀ yìí:


Ìwulò – ohun tí a rí kò ní ìwulò tàbí ìtumọ̀ àyàfi tí a bá gbé ìtunmọ̀ lé e lórí ní tipá, ó ní láti gbà ìṣe ìwà nínú, nítorí kò ní àkọsílẹ̀ àṣà. Ìtunmọ̀ rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí a fi àwòrán gbé kalẹ̀ tí sì ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ fínnífínní. Ìwà – (láti jẹ́) jẹ́ àkoónú ẹwà. Ní inú ìwà ni ẹwà ti ń ṣáná


Àfiwé Tààrà - ọnà ifèrò ọkàn ẹni hàn tí ìpele rẹ̀ yàtò sí ti orúkọ, àká òótọ́ àti ìtunmọ̀ fún ìfèrò ọkàn ẹni hàn. 


ÌMỌRÍRÌ - Ní mímọ rírì ẹwà iṣẹ́ ọnà Yorùbá, o nílò ojú àti orí. O nílò ojú òde pẹ̀lú (ojú inú) láti lè mọ iyì iṣẹ́ ọnà. Méjèèjì ni ó wúlò pẹ̀lú òye  àkànlò èdè, gbólóhùn àti ìtàn Yorùbá. 


Orí náà gbọdọ̀ jẹ́ ti òde, bẹ́ẹ̀ ni orí inú. A nílò láti pa gbogbo ìwà tí a dárúkọ ní òkè yìí pọ̀ kí a lè mọ̀ rírì ẹwà àti àrà tí oh wà nínú iṣẹ́-ọnà Yorùbá. 

©Will Rea