Àdìrẹ Ọlọ́bà

Ọ̀kan lára àwọn aṣọ Yorùbá tí ó wuyì tí ó sì dá yàtọ jùlọ ni aṣọ tí wọ́n máa ń rẹ, tí wọ́n ń pè ní Àdìrẹ. Àdìrẹ ní orúkọ tí wọn máa ń pe èyí kéyìí aṣo tí wọn bá rẹ, ṣùgbọn wọn a máa lò ó ní pàatàkì julọ fún aṣọ tí wọ́n bá rẹ ní aró kíun. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ọgbọn à ti tún aṣọ lo, kí aṣọ náà sì túbọ̀ ní kìmí lára ni wọ́n fi máa ń pa aṣọ ní aró, ṣùgbọn àdìrẹ bẹ̀rẹ̀ sí ní di ohun tí àwọn ènìyàn ń fẹ́ láàyè ara rẹ̀. Ara aṣọ náa jẹ́ ẹ̀yà aṣọ olówùú ẹyọ méjì tí wọ́n rán pọ̀ láti ní igun tí kò dá mọ́nrán. Àwọn obìnrin ni wọ́n máa ń pa aṣọ láró, ní àwọn ilé ì-pa-aṣọ-láró tí oh tóbí ní Ìlà oòrùn. Aró tí wọ́n fi ń pa aṣọ máa ń wù fúnra rẹ̀ ní apá gúsù Yorùbá. Wọn a se ìdí ewé aró àti caustic soda nínú omi kí wọ́n tó fi aṣo tí wọ́n ti di sílẹ̀ sínú rẹ̀.

Bátánì tí ó máa ń wà lára àdìrẹ jẹ́ èyí tí wọ́n dìídì ṣe sí ara rẹ̀ kí ó tó di wípé wọ́n rẹ ẹ́. Ọ̀nà méjì pàtàkì ni ó wà. Àdìrẹ oníko, tí wọ́n máa ń lo Raffia fún tàbí kí wọn rán an. Nínú kí wọ́n fi nǹkan sí inú aṣo tí wọ́n dì (Àdìrẹ Eléso) tàbí kí wọ́n di aṣọ náà kí ó le, kí aró mà sì lè de àwọn ibi tí wọn bá di (Adire Ẹlẹlọ).. Irúfẹ́ ìlànà yìí ni ó so mọ èyí tí wọn máa ń rán. Wọn a di aṣọ náà, wọn a sì rán an láti dá àrà sí ara rẹ̀ kí ó lè ní bátánì (Ẹlẹ́sun). Àdìrẹ Ẹlẹ́kọ ní wọn máa n fi sítáàṣì sí. Ó ṣé ṣekí ó jẹ́ pé ọdún 1910 ní èyí bẹ̀rẹ̀. Ọ̀nà méjì ní Ẹlẹ́kọ, nínú kí wọ́n fi ọwọ́ dárà síi lára tàbí kí wọn lo páli, iké tàbí irin. Èyí tí wọn fi ọwọ́ dára sí ní o máa ń wá láti Ìbàdàn jùlọ, ṣùgbọn èyí tí wọn máa ń lo ike, irin tàbí páli fún jẹ́ èyí tí àwọn Abẹ́òkúta gbájúmọ́ jùlọ ní ṣíṣe.


Aṣọ èyí tí wọn máa ń lo ike, irin tàbí páli yìí ni a mọ̀ sí Ọlọ́ba (ní èyí tí ó túnmọ̀ sí oní-ọba). Bákan náà ni wọn tún máa ń pè é ní Jubilee. Àwọn àwòrán tí ó wọ́pọ̀ lára rẹ̀ ni Ọba Birítíìṣì (King George V) àti Olorì (Queen Mary). Aseyẹ àyọ́jọ odún márùndínlọ́gbọn wọn ní ọdún (1935) ni wọn ṣe jákèjádò gbogbo Ìlú British pẹ̀lú oríṣ̀ìíríṣìí nǹkan tí ó ní àwòrán ọba àti Olorì nínú gbàgàdà. Àwọn tí wọn sẹ àdìrẹ ní Abẹ́òkúta rí èyí, wọn sì ro wípé àmì aṣọ ńlá ni èyi. Àwọn àwòrán mìíràn ni ó wà lára aṣọ yìí, bíi Ẹṣiń oní ìyẹ́ (Al Baraq) tí ó gbé Mohammed lọ sí Mecca. Àwọn ohun tí wọn kọ yìí ń sọ bí ẹni tí ó wọ̀ ọ́ ṣe tó ní àwùjọ.

©The Trustees of the British Museum