Ìtẹ̀dó náà

Gbọ̀ngàn John Randle máà sọ agbègbẹ̀ Màrínà àti Oníkán dí ibi pàtàkì tí àwọn ẹnìyàn yóò máa rín ìrìnàjò afẹ́ wá. A fii sọlẹ̀ sí ìdojúkọ National Museum ní àdúgbò Oníkán, ní ìlú Èkó. 

Gbọ̀ngàn yìí súnmọ́ etí National Museum Èkó, àti Tafewa Balewa Square, bẹ́ẹ̀ni ó tún súnmọ́ àwọn ibi tí ìgbáṣàga wọ́pọ̀ sí bíi Freedom Park, Onikan Stadium, àti the Festac ’77 archive.

All images © Ademola Olaniran & Jide Atobatele

Àwọn ohun ìní

A gbé e ka orí ilẹ̀ tí ó tóbi, àwọn ohun ìní tí ó wà ní ibi iṣẹ́ náà ní ìwọ̀nyí:

– Ààye ìsàfihàn tí ó wà títí laí, àti ààyè ìṣàfihàn tí ó wà fún ìgbà díẹ̀

– Yàrá ìkàwé tí ó ní awọn ohun èlo àfojúrí àti àwọn ohun èlò alo díjíìtì

– Àwọn yàrá tí ó ṣe é lò fún ohun púpọ̀

– Ààye fún ìdánílẹ́kọ̀ọ́ (sẹ́mínà) àti iṣe-ṣíṣe

– Ibi ìtajà àti yàrá ìrọgbọ̀kú

– Ilé oúnjẹ́ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ - ọkan nínú èyí tí yóò wà ní ìta gbangba, tí yóò sì ní ààye fún ilé ounjẹ/ọtí

– Ibi ìlúwẹ̀ẹ́ tí ó jẹ́ ti gbogboògbò

– Ààye tí ó fẹ̀ fún gbọngàn ọjà

– Ibi igbọ́kọ̀ sí

Ipò tí iṣẹ́ dé dúró ní Gbọ̀ngàn náà

Ilé Gbọ̀ngàn John Randle

Ṣẹ́ẹ̀lì Ilé ìṣàfihàn ti parí. Iṣẹ́ ẹ Ibi ìṣàfihàn Tyrolean náà ti parí dé ìta. A ti bẹ̀ẹ̀rẹ̀ àtòpọ̀ Ohun tí a fẹ fi gbé àtẹ agbàwòrántàn onírin dúró dé ààyè kan ṣùgbọ́n à ń dúró kí àtòpọ̀ agbàwòrántàn náàn parí. Ní inú ilé, à ń ṣe àwọn ìlẹ̀kùn, fèrèsé, pípààlà ní inú ilé, àjà, ògiri, àti ilẹ̀ lọ́wọ́.

Ibi ìlúwẹ̀ẹ́ àti ibi eré ìdáraya

Iṣẹ́ lórí Ibi ìlúwẹ̀ẹ́ àti ṣísọ di ọ̀tun àwọn ohun ìní ti parí, à ń lẹ̀ táílì ibi ìlúwẹ̀ẹ́ lọ́wọ́, pẹ̀lú táìli ilé ìwẹ̀ àti àwọn yàrá ìpàṣọdà. Iṣẹ́ àjà ibi tí a sẹ̀tò fún eré ìdárayá àti iṣẹ́ gíláàsì ìwájú ilé oúnjẹ náà ń lọ lọ́wọ́.

Iṣẹ́ Ìta gbangba

Iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́ lóri bí agbègbè ilé iṣẹ́ yóò ṣe máá fi gbogbo ìgbà wuni pẹlù tí gbogbo ewé yóò si máa tutu. Iṣẹ́ gọ́tà lílà náà ń lọ lọ́wọ́ lẹ́yìn náà ni gbogbo ilẹ̀ yóò di wíwọ́.

Wíwòyíká Gbọ̀ngàn

Àti wá sí ibi-iṣẹ́ yìí kò tíì dán mọ́nran nítorí iṣẹ́ tó ń lọ lọ́wọ́. Síbẹ̀, àwọn ènìyàn kọ̀kọ̀kan ti wá yẹ gbọ̀ngàn náà wo, bíi àkójọpọ̀ àwọn ọmọ ilé ìwé, àwọn ará Èkó, Àwọn ẹnìyàn jàǹkànjàǹkàn àti àwọn ìlú mọ̀ka kọ̀ọ̀kan. 

Lára àwọn wọ̀nyí ni Ọ̀jìnmí ọjọ̀gbọ́n Wole Soyinka, Gomínà Ìpínlẹ̀ Èkó, Sanwo Olu, Lissant Bolton àti Julie Hudson ti British Museum, Aṣojú ilẹ̀ Faransé, àwọn onígbọ̀wọ́ John Randle, àti Federal Minister of Tourism.