Babajide Sanwoolu, Gómínà Ìpínlẹ̀ Èkó
Iṣẹ́ àkànṣẹ yìí tí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó fi tàṣẹtàṣẹ sọlẹ̀, wà ní ibití ó rọrùn púpọ̀ láti dé ní àárin gbùngbùn àdúgbò Màrínà àti Oníkán.
Fún bíi àádọ́rùn-ún ọdún, Gbọ̀ngàn John Randle ní Oníkán ní Èkó dúró gẹ́gẹ́ bí ibi ìgbafẹ́ tí àwọn ènìyàn ti máa ń lúwẹ̀ẹ́, ṣafẹ́, tí wọ́n sì máa ń dá ara wọn lárayá. Ibi ìúwẹ̀ẹ́ tí ó wà ní ibẹ̀ ni èyí ti Dókítà. John Randle fi lọ́lẹ̀ pẹ̀lú èròńgbà láti máa lò ó, láti kọ́ àwọn ará Èkó tí wọ́n bá fẹ́ kọ́ bí a ṣe ń lúwẹ̀ẹ́. Ibi ilúwẹ̀ẹ́ kò ní yọ kúro nínú àtúnṣẹ tuntun sí ibi-iṣẹ́ náà.
Gbọ̀ngàn yìí máa ní àwọn ohun ìní lọ́pọ̀lọpọ̀, lára èyí tí ibi ìsàfihàn tí ó gbayì yóò wà.
Àlàyé kíkún nípa ọjọ́ ìṣíde, wákàtí tí yóò jẹ́, àti owó ìwọlé fún ìṣíde ọdún 2021 yóò máà tẹ̀ta láìpẹ́. Kọ́ Síi...