“Gbọ̀ngàn John Randle, jẹ àkọ́kọ́ lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ àfojúsùn tí a ti là kalẹ̀ láti ṣe ìpamọ́ ogún-ìbí Yorùbá, láti ara àyẹ́sí àti ìpamọ́ ìtàn àti àṣà, àtúgbédìde àwọn ibi àtijọ́ tí wọ́n ti di àlòpatì, àwọn ibi ìgbáfẹ́ ará ìlú àti àtúngbédìdì iyì ìlú. Oníkán máa dí ibi ìyànjú fún àdúgbò tí ó jojúnígbèsè tí ó sì fi àyè gba ìrìnkiri afẹ́ ní àárín gbùngbùn ìlú Èkó.”

Babajide Sanwoolu, Gómínà Ìpínlẹ̀ Èkó

©The National Archives UK

Nipa Gbọ̀ngàn Náà

Ìtàn Gbọ̀ngàn J. Randle


©The National Archives UK

Bí a Ṣe Kọjú sí Ìkọ́lé

ÌSỌNÍṢÓKÍ

Àwọn Ayàwòrán Ilé, SI.SA ni wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ èyí Gbọ̀ngàn John Randle fún Àṣà àti ìtàn Yorùbá darapọ̀ mọ́ iṣẹ́ àkànṣẹ ìṣàtún ìlú tí ó wáyé ní àárin gbùngùn ìlú Èkó, ọ̀kan lára ibi tí ó ń ṣe àfihàn bí ìlú Èko ṣe dára tó. Ohun tí ó jẹ iṣẹ́ àkànṣe yìí lógun ni láti ríi dájú pé wọ́n mú àtúnṣe bá ibi ìlúwẹ̀ẹ́ tí ó ti wà láti ọdún 1928, nípa lílo àwọn ohun ìgbàlódé láti tún un ṣe, kí wọn sì kọ́ ilé sí orí 1,000 sq. m.pẹ̀lú  ibi ìṣàfihàn tí ó ń sọ nípa ìtan àti àṣà Yorùbá nípa lílo ìtàn ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìràn náà dé orí ìtàn ìsìnyí títí dé ọjọ́ iwájú. Èyí ni wọ́n gbé kalẹ̀ sí ibi tí King George V Park ṣe àwárí ní sẹńtúrí kéjìdínlógún tí wọ́n sì kọ́ ọ ní ṣẹ́ńtúrì tí ó kọjà. 


Ìyàwòrán ilé  ibi-iṣẹ́ yìí ṣe àmúlò ọ̀nà ìkọ́le àti ìṣọ̀nà àtijọ́, tí ó si lo àfiwé tààrà aláfojúrí láti ṣe àgbéjáde iṣẹ́ ọnà tí ó rinlẹ̀ àti ìmọ̀ ìṣẹ̀dá èdè àti àṣà. Ìrísí ilé náà dàbí ayé, ó bẹ̀rẹ̀ láti ayé, ó sì tẹ̀ sí ìwájú bíí ìgbàtí ó ń tẹ sí ìtẹ̀síwájú, tí ó sì ṣe àfihàn bí ìtèsíwáju ṣe jẹ́ ọkàn lára àwọn nǹkan tih mọ̀ mọ àwọn Yorùbá. tyrolean tí wọ́n pa láró ní wọ́n fi parí ilé náà, ní èyí tí o mú kí ó jọ irúfẹ́ àrà ilé alámọ̀ tí ó wà nínú àṣà ilékíkọ ní ilẹ̀ Yorùbá. Àtẹ onírin tí ó bo ojú ìwájú ilé náà dúró fún ìtàn ìgbà tí iṣe ohun ní ọ̀nà tih ó tọ̀ jẹ́ nǹkan ojoojúmọ ní ìgbésí ayé àwọn Yorùbá. Páànù ilé aláwọ̀ ewé ní ó so ilé náà mọ́ ilẹ̀, èyí kò ní jẹ́ kí orú pọ̀ ní inú ileh náà, yóó sì tún fi àyè sílẹ̀ ní ìtà fún àjọsepọ̀. 


Ibi ìlúwẹ̀ẹ́ àti ilẹ̀  tí ó wà ní ibi-iṣẹ́ náà máa dúró gẹ́gé bíi ohun tí yóò máa fa ìbísii wá fún àdúgbò náà tí yóò sì máa mú kí ọkàn àwọn ènìyàn máa fà sí ibi afẹ́ tí ó wà ní àárín gbùngbùn èkó. Gbọ̀ngàn John Randle máa gbèrò láti jẹ́ kí àwọn ará ìlú mọ̀ nípa ọlá tí ó wà ní inú àṣà àti ìtàn Yorùbá, ipa tí ó ti kó ní inú iṣẹ́ ọnà, orin, ẹ̀sìn, èdè; ibi tí ó ti pẹ̀ka dé ní inú ayé láti ara àṣà àti pàtàkì rẹ̀ pàápàá ní fifi ogún-ìbí sílẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la ìran náà.

“British Museum ti gbárùkù ti ìdàgbàsókè Gbọ̀ngàn John Randle fún Ìtàn àti Àṣà Yorùbá láti ìgbà tí wọ́n ti bẹ̀ẹ̀rẹ̀ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ń fi ojú sọ́nà fún ìgbà tí wọn yóò ṣi ibi-iṣẹ́ alárà tí ó wà ní àárin gbùngbùn ìlú Èkó yií fún ìlò ní ọdún 2021. Ohun agbáṣàga yìí máa pèsè ààyè tuntun tí ó wuyì láti tubọ̀ ṣe àyẹ́sí àti àwárí ohún-ìbí Yorùbá, àtijọ́ àti ìsìnyí, yóò sì tubọ̀ pèsè àǹfààní fún ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti àjọṣepọ̀ tí ó dára láàárín Nàìjíríà àti UK.”

Hartwig Fischer, Olùdarí, British Museum

©Ajibola Fasola / Shutterstock.com

Ṣíṣe àgbékalẹ̀ ogún ìbí Yorùbá 

Kò sí ìtàn àwọn ènìyàn Yorùbá kan ṣoṣo. Láti ní òye nípa ìtàn àwọn ènìyàn Yorùbá, ni láti ní òye bí ìdánimọ̀ àwọn ìran Yorùbá ṣe bẹ̀rẹ̀ tí ó sì di bí ó ṣe wà pẹlú sẹ́ńtúrì ìtàn tí ó sì tàn ká gbogbo orígun mẹ́rẹ̀rin àgbáyé láti Nàìj́ríà. Láti ní òyé ogúnlọ́gọ̀ àwọn ẹ̀ka èdè tí ó wà ní inú èdè náà, àti àwọn oríṣìíríṣìí àṣà àti ayẹyẹ tí ó wà ní abẹ́ òrùlé ‘Yorùbá’


Gbọ̀ngàn John Randle fún Àṣà àti Ìtàn Yorùbá , máa jẹ́ ìrírí aláìlẹ́gbẹ́ ní ìpínlẹ̀ Èkó – Ibi tí àṣà sodo sí tí ó sì múnilọ́kàn tí yóò fi ìtàn ìran Yorùbá han àwọn alejò – ọ̀kan lára àwọn ìran tí ó rinlẹ̀ jùlọ ní Nàìjíríà. Àwọn tí ìmọ̀ wọn jinlẹ̀ nínú èdè Yorùbá àti àwọn tí ìmọ̀ wọn ò jinlẹ̀ tó máa jùmọ̀ ní àǹfààní láti mọ̀ nípa àwọn ìtàn gidi, ìtàn ìwásẹ̀ àti àjogúnbá ìṣẹ̀ṣe àwọn Yorùbá,láti orí  ìsàbápàdé ìrírí  oríṣìiríṣìí tí ó jẹ́ mọ́ àwọn ọdún ìbílẹ̀ alárà-ọ̀tọ̀ Yorùbá, títí dé orí àwọn nǹkan àṣà, ìtàn àti àwọn bàbáńlá Yorùbá.  


Gbọ̀ngàn John Randle máa jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ibi-iṣẹ́ ìbílẹ̀ àkọ́kọ́ irú ẹ̀ ní ìlú Èkó. Gẹ́gẹ́ bí ó ti yàtò sí ilé àkójọpọ̀ ohun ìgbàanì, ibi iṣẹ́ náà máa ṣe ìpèsè ààye fún oríṣìíríṣìí nǹkan bíi ètò ìkọ́ni, iṣẹ́ ọnà ṣíṣe àti òde orín lọ́kanòjọ̀kan. Àwọn ìtàn tí ibi-iṣẹ́ yìí ní láti jẹ́ kí àwọn àlejò mọ̀ nípa rẹ̀ máa yà wọn lẹ́nu, jọ wọn lójú, á sì ṣe wọn ní kàyéfì púpọ̀, èyà-kí-ẹ̀yà tó wù tí àlejò náà ìbá jẹ́.

©Ajibola Fasola / Shutterstock.com

ibi ìṣàfihàn láíláí

Àṣà Yorùbá jẹ ọ̀kan lára àwọn àṣà ìgbàlódé tí ó ṣe pàtàkì sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Bí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣe ń lajú ní wàràwàrà, ó ṣe pàtàkì láti kọ́ àwọn ògo wẹẹrẹ nípa bí àwọn ohun ìní Yorùbá ṣe ń fún àwọn olórin, òṣèré àti àwọn oníṣẹ́-oní ní ìṣípaya ní òde òní. Nípa ṣiṣe àyẹ́sí èdè, ìbọ, àwọn ọdún ìbílẹ̀, òrìṣà àti àwọn alálẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá ní irú àkókò yìí, máà fún ni ní àrídájú pé Ogún-ìbí àṣà àti ìtàn Yorùbá kò ní parẹ́ títí láí ní ìlú Èkó. 


Gbọ̀ngàn John Randle máa jẹ́ ibi ìrántí àti ibi ìpàdé fún àwọn ọmọ Yorùbá àti àwọn ọmọ Áfíríkà láti Cuba, Brazil, Haiti, America àti Caribbean, àti gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà, nípa sísọ ìlú Èkó dí ibúdò ìrìnrìnàjò afẹ́. 

“Gbọ̀ngàn John Randle jẹ́ àgbékalẹ̀ ayérayé fún ọlàjú, Yorùba, àìparun ìtàn àṣà Yorùbá tí ó lọ́ọ̀rìn  àti ìpa Yorùbá. Àwọn ohun tí Gbọ̀ngàn yìí bá ń ṣe àfihàn máa ṣe àgbéjáde ìmọ Yorùbá, àwọn nǹkan ẹ̀mí àti ìwàláyé, tí yóo sì tún pèsè ààyè fún gbogbo ènìyàn láti ní ìrírí, ẹwà, ògo, àti ìyanu, ohun ìyebíye àgbáyé aláìlákàwé.”

Ọ̀jọ̀gbọ́n Jacob Kẹ́hìndé Olúpọ̀nà

©Valentine Ojiaku

Ìjíṣẹ́

Gẹ́gẹ́ bí ìlú tí ó gbajúmọ̀ jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ní èyí tí ó sì jẹ́ wí pé ẹ̀yà Yorùbá ni ó wọpọ̀ jùlọ ní ibẹ̀, Èkó jẹ́ ibi tí ó dára jùlọ láti gbé ohun agbáṣàga sí, ní èyí tí Gbọ̀ngàn John Randle dúró láti ṣe. Ilù Èkó jẹ́ ìlú tí a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó níí ṣe pẹ̀lú ohun ìní Yorùbá, èyí jẹ́ àǹfààní ńlá fún ìlú Èkó latí ṣe àjọyọ̀ ohun tí ó so àwọn àti àṣà ilẹ̀ Yorùbá pọ̀, pẹ̀lú Ogún ayérayé tí í ṣe Ibi-Iṣẹ́ Yorùbá. 


Agbára ayárabíàṣá, ìfọ̀kànsìn àwọn aráìlú àti onírúurú ẹ̀yà ní ilẹ Yorùbá jẹ àmì ẹmì ọ̀kan-ò-jú-ọkan-lọ tí ó wà ní ìlú Èkó. Fún ìdi èyi, ibi-iṣẹ́ yìí yóò túbọ jé ibi àmì àjọṣepọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà ní Olú-ìlú yìí. 

 

Àṣà Yorùbá jẹ ọ̀kan lára àwọn àṣà ìgbàlódé tí ó ṣe pàtàkì sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Bí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣe ń lajú ní wàràwàrà, ó ṣe pàtàkì láti kọ́ àwọn ògo wẹẹrẹ nípa bí àwọn ohun ìní Yorùbá ṣe ń fún àwọn olórin, òṣèré àti àwọn oníṣẹ́-oní ní ìṣípayá ní òde òní. Nípa ṣiṣe àyẹ́sí èdè, ìbọ, àwọn ọdún ìbílẹ̀, òrìṣà àti àwọn alálẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá ní irú àkókò yìí, máà fún ni ní àrídájú pé Ogún-ìbí àṣà àti ìtàn Yorùbá kò ní parẹ́ títí láí ní ìlú Èkó. 


Gbọ̀ngàn John Randle máa jẹ́ ibi ìrántí àti ibi ìpàdé fún àwọn ọmọ Yorùbá àti àwọn ọmọ Áfíríkà láti Cuba, Brazil, Haiti, America àti Caribbean, àti gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà, nípa sísọ ìlú Èkó dí ibúdò ìrìnrìnàjò afẹ́. 

“Ní tààrà àti lọ̀nà àfiwé, ìgbékalẹ̀ àti ìpolówó àwọn iṣẹ́ Yorùbá gbọdọ̀ jọlá ẹwà ẹnu àti àṣà àròjinlẹ̀ wọn. (Ó yẹ ká ní) Gbàgede kan tí a yà kalẹ̀ fún ṣíṣàlàyé (àti fífi ṣeré ìtàgé pàápàá) àwọn oun ìjìnlẹ̀ Yorùbá bíi Orí, àṣẹ, aṣọ, Ọ̀ṣun àti “ìbẹ̀rẹ̀” ilé ayé pẹ̀lú oríkì. Níni yìí ni oun mèremère, ìwárí oun àtijọ́ àti ìtàn ti pàdé, tí ó sì lè la ọ̀nà fún àgbọ́yé àṣà àti ìtàn Yorùbá…
“Àwọn àròjinlẹ̀ tó ń darí ìgbékalẹ̀ àwọn iṣẹ́ Yorùbá gbọdọ̀ jẹ́ láti fà àti láti dáàbòbo ìfẹ́ inú àwọn tó ń gbé àṣà Yorùbá lárugẹ; kìí ṣe fún àwọn àlejò/awòran àtọ̀únrìnwá ìgbàdégbà nìkan tí wọ́n máa ń lérò láti rí irú ẹ̀dà oun tó ti mọ́ wọn lára láti gbàgede oun àtijọ òkè òkun.”

Rowland Abíọ́dún

Àwọn Onímọ̀ràn Àkónú Ìpìlẹ̀ fún Gbọ̀ngàn John Randle

Gbọ̀ngàn John Randle ni a ṣe ìpilẹ̀ ẹ̀ pẹ̀lú àjọṣepọ̀ ìgbìmọ̀ olóye kan tí a kójọ láti orígun mẹ́rin ayé. Onímọ̀ tó ga jù níbẹ̀ ni Rowland Abíọ́dún, tó jẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n John C. Newton fún Iṣẹ́ Ọnà Afrikà ní Amherst College, àti olùkọ́ àgbà ní Yunifásitì Ifẹ̀. Ìwé wọn Yoruba Art and Language: Seeking the African in African Art ni ó ṣe àgbékalẹ̀ tí a kọ́ Gbọ̀ngàn John Randle lé lórí.  

 

Ọ̀jọ̀gbọ́n Jacob Olúpọ̀nà ni Onímọ̀ Ìjìnlẹ̀ ti Àṣà Ẹ̀sìn Ilẹ̀ Áfŕikà ní Harvard Divinity School. Wọ́n jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ní èrò àti àròjinlẹ̀ Yorùbá.  

 

Henry John Drewal jẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n Àgbà ní Yunifásití ti Wisconsin ní Madison. Fún ọdún pípẹ́ ni wọ́n ti jẹ́ olórí oníwádìí ìjìnlẹ̀ iṣẹ́ ọnà àti àṣà Yorùbá, tí wọ́n sì ń ṣe olóòtún oríṣiríṣi ìṣàfihàn káàkiri àgbáyé.  

 

Dr Will Rea ni a bí ní ìlú Ìbàdàn, tí wọ́n sì ti ṣiṣẹ́ fún ọdún púpọ̀ ní ìlú Ekiti. Wọ́n ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ báyìí ní School of Fine Art, History of Art, and Cultural Studies ní Yunifásitì Leeds ní UK.

Àwọn ìgbìmọ̀ òṣìṣẹ́ ilé àkójọpọ̀ ohun ìgbaanì fún Gbọ̀ngàn John Randle ni, Dr Will Rea (aṣàkóso ìgbìmọ̀ òṣìṣẹ́ ilé àkójọpọ̀ ohun ìgbaanì) Sir Martins Akanbiemu (Adarí Iṣẹ́, Àṣà àti Ìṣe), Nath Mayo Adediran (Adarí kejì iṣẹ́, Yorùbá Òde Òní), Iheanyi Onwuegbucha (Adarí kejì iṣẹ́, Yorùbá Òde Òní), Adérẹ̀mí Adégbìtẹ́ (Adadiŕ Kejì iṣẹ́, Yorùbá Òde Òní) àti Oyíndà Fákẹ́ye (Adarí kejì Iṣẹ́, Yorùbá Ọjọ́ Ọ̀la) àti Àwọn Olùkópa Ìdarí Ẃalé Lawal, Ọmọ́yẹmí Akéréle àti Tòkunbọ̀ Akélére. Àwọn tí wọn kọ tí wọ́n sì ṣe àdàkọ àtòpọ̀ awọn ìtàn/ìṣẹ̀lẹ̀ fún ìṣàfihàn láíláí ni by Rótìmí Fáwọlé àti Kọ́lá Túbọ̀sún.