Ẹgbẹ́ Mbari tí Ìbàdàn

Àárín Ọdún 1950 sí 1970 ṣe pàtàkì púpọ̀ sí ìdàgbàsókè ìtàn iṣẹ́-ọnà òde òní àti lítíréṣọ̀ ilẹ́ Áfíríkà. Ìṣèlú, àṣà, èrò báyéṣerí, ìdáràsí, àti ìmọ̀ báyéṣerí agbègbè tí o bí ìdàgbàsókè iṣẹ́-ọnà òde òní ní ilẹ́ Afíríkà wáyé láàárín àkókò kan náà pẹ̀lú ìbí lítíréṣọ̀ òde òní ní orílẹ̀ ẹ̀yà àgbáyé náà. Ní àkókò yìí kan náà, onírúurú ọgbọ́n-inú àtọ́wọ́dọ́wọ́ àkopọ̀-èrò láàárín oníṣẹ́-ọnà àti òǹkọ̀wé ni ó wáyé.


Àjọṣepọ̀ tí ó dámọ́rán gbilẹ̀ ní Ìbàdàn nípasẹ̀ ẹgbẹ́ Mbárí. Ẹgbẹ́ yìí, bá Ìwé Ìròyìn Afẹ́ Black Orpheus ṣe pọ díẹ̀, Bákan náà ni wọ́n dúró gẹ́gẹ́ bí atẹ̀wétà ní àsìkò ìtẹ̀jáde àkọ́lé mẹ́tàdínlógún láti ọwọ́ àwọn òǹkọ̀wé Áfíríkà ní ọdún 1960. Àwọn ìwé tí wọ́n tẹ̀ jáde wọ̀nyí ní iṣẹ́-ọnà tí wọ́n yà gàdàgbà sí ẹ̀yìn wọn! Èyí bẹ̀rẹ̀ láti orí àtẹ̀jáde oríkì Bakare Gbadamosi tí oh pè ní Léon Damas’s African Songs of Love, War, Grief, and Abuse ní èyí tí ó ṣe àfihàn àwọn iṣẹ́-ọnà Georgina Betts ní ẹ̀yì ìwé náà. Eré oníṣẹ John Pepper Clark tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Songs of a Goat, náà ṣe àfihàn àwọn àwòrán ajúwe ìfihàn alálàyé Susanne Wenger ní púpọ̀ nínú àwọn ojú ìwe rẹ̀.  Ìwé eré oníṣe Wole Soyinka tí ó pe àkọlé rẹ̀ ní Three Plays náà tún jẹ́ ìwé mìíràn, tí ó ní àwòrán Uche Okeke àti Ibrahim El Salahi nínú.


Ṣíṣe iṣẹ́ lórí ìṣàfihàn nígbangba àti ìpàtẹ Gbọ̀ngàn John Randle, ṣe àfihàn díẹ̀ nínú ìbáṣepọ̀ yìí láàárín oníṣẹ́-ọnà àti òǹkọ̀wé tí ó ti wà fún bí ọgọ́ta ọdún ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ìbáṣepọ̀ yìí túbọ̀ gbèrú sí i nínú ẹgbẹ́ Mbárí, bákan náà ni àṣeyọrí àjọṣepọ̀ iṣẹ́ ọnà àti lítíréṣọ̀ tí ó wáyé nínú àtẹ̀jádé ẹgbẹ́ yìí dálórí ìbáṣepọ̀ tuntun tó làmìlaaka láàárín àwọn oníṣẹ́-ọnà àti àwọn òǹkọ̀wé ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, àti tayọ Ìbàdàn. 


Ní ààyè kan, àwọn oníṣẹ́ ọnà bíi Bruce Onobrakpeya, ẹni tí ó ti fi ìgbà kan ṣe àfihàn ìtàn àlọ́, tih ó sì ṣe àmúlò àjọṣepọ̀ tuntun yìí nípa lílo iṣẹ́ àwọn òǹkọ̀tàn, akéwì àti àwọn akọ̀tàn gẹ́gẹ́ bí orísun ìmísí. Ní ọ̀nà mìíràn ẹ̀wẹ̀, àwọn òǹkọ̀wé tọ àwọn oníṣẹ́ ọnà lọ láti sọ nípa èrò wọn kí wọn sì mú àwọn oǹkàwé wọn lọ́kàn. 


Ọ̀nà ìbáṣepọ̀ tuntun yìí ṣe àmúwaáyé ọkan pàtàkì lára irúfẹ́ iṣẹ́ ọnà òde-òní ní Áfíríkà; Ìfàwòránsọ̀tàn. Ìfàwòrásọ̀tàn di gbajúgbajà, ó sì túbọ̀ ṣe okùnfà àjọṣepọ̀ oníṣẹ́-ọnà àti òǹkọ̀wé nípasẹ̀ àwọn Àlàyé inú Ìwé. Ìbáṣepọ̀ tuntun iṣẹ́ ọnà àfojúrí àti lítíréṣọ̀ yìí tún bí ojúwòye ìfàwòránsọ̀tàn ajẹmọ́-àwàdà tí ó ta àkòrí akọni yọ, sí àwọn àwòrán aṣàlàyé ajẹmọ́ ìṣẹ̀lú àwùjọ.


Àjùmọ̀ṣẹ̀dá àwọrán pẹ̀lú àwọn òǹkọwé nìkan kọ́ ní àwọn ọníṣẹ́ ọnà ń ṣe, wọ́n tún a tún máa kópa nínú ìgbéṣẹ̀ ìwòye ìṣàlàyé tí ó tẹramọ́ ìgbéjáde lọ́nà pàtó àti ọrọ̀ ajé ètò àti èdè àfojúrí látàrí ṣíṣe àgbékalẹ̀ ní ọ̀nà tí ọ̀rọ̀ díà ni yóò jáde ṣíbì ìtumọ̀ púpọ̀ bí ìgbàtí ọ̀rọ̀ náà pọ̀ ni yóò jáde. Àwọn ìgbésẹ̀ bí i ògbufọ̀, ìsọníṣókí, ìmurọrùn, yíyàsọ́tọ̀ ni wọ́n tẹramọ́.


Bruce Onobrakpeya pẹ̀lẹ́kùtù yànnàná èrò púpọ̀ nínú àwọn òǹkọ̀wé sí ìtẹ̀jáde àti àwòrán afẹ̀dùnọkàn hànde. Ṣíṣe ìwadìí fún ìṣàfihàn nígbangba àti ìpàtẹ Gbọ̀ngàn John Randle, mo lo ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú Ọníṣẹ́ ọnà Bruce Onobrakpeya, tí mo sì ṣe àgbéyẹ̀wò àkójọpọ̀ iṣẹ́-ọnà àti lítíréṣọ̀ rẹ̀. Àkoónú Àkójọpọ̀ yìí ní àwọn ìfàwòrányafọ́tò tàbí ìṣatúnmọ̀ àfojúrí àwọn ewì, ìtàn kékèké àti àlọ́ láti ọwọ́ àwọn ònkọ̀wé àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà, pàápàá láti inú ẹgbé Mbárí. Yàtọ̀ fún àwọn iṣẹ́ àkàṣe wọ̀nyí, àwọn iṣẹ́ mìíràn ṣàmúlò èrò-inú, èyí tí wọ́n hun pọ̀ mọ́ ọgbọ́n àtinúdá àlàkalẹ̀, láti sọ àwọn ìtàn àlọ Yorùbá èyí tí àwọn oǹkọ̀wé bíi Wole Soyinka, D.O Fagunwa Amos Tutuola, àti àwọn ìíràn pilẹ̀ di ìtàn gidi.


Ó ṣe àgbékalẹ̀ àwọn èdè ìperí tuntun tí ó jẹ mọ iṣẹ́ ọnà – Álífábẹ́ẹ̀tì Urhobo tí ó sì pa èyí pọ̀ mọ́ ìfàwòránsọ̀tàn àrà ọ̀tọ̀ nínú àrà kan tí kò jẹ́ òótọ́. Ní ìgbà mìíràn, iṣẹ́ àwọn òǹkọ̀wé wọ̀nyí a máa ṣe àlábàápàdé ìfarapẹ́ra ìgbéròsíta nínú àrà ìfàwòránsọ̀tàn rẹ̀.


Ṣíṣe iṣẹ́ lórí Gbọ̀ngàn John Randle, ti jẹ́ kí n ní ifẹ́ sí  bí àwọn oníṣẹ́ ọnà ṣe máa wo iṣẹ́ ọnà alátinúdá àti àwọn ohun tí ó rọ̀ mọ́ ọn nípa lílo àfojúrí àti àfetígbọ́, gbigbẹ́gilére àti eré ìsẹ́. Mo sì gbàgbọ́ pé ọ̀rọ̀ ṣì pọ̀ láti sọ lóri èyí, kò kan í ṣẹ ọ̀rọ̀ lórí ìbáṣepọ̀ láàárí iṣẹ́ ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ àti iṣẹ́ ọnà àtinúdá.

©Will Rea
©Will Rea
©Will Rea