Àìmàsìkò: SummaryWale Lawal

Fún ìgbà díè báyìí, ìkan lára àwọn ọ̀rọ̀ tó ta kókó jùlọ nínú àwọn ilé àṣà lágbàáyé ni ọ̀rọ̀ nípa ibi tí àwọn oun mèremère Afríkà yẹ kó wà. Oríṣi ìtẹ̀dó méjì ló wà: àwọn tó gbàgbọ́ pé ó yẹ kí á dá àwọn oun mèremère yìí padà àti àwọn tí kò gbà, tí wọ́n ń lo àwáwí pé kò sí ààyè láti tọ́jú iṣẹ́ ọnà ní àwọn orílẹ̀ èdè Áfríkà. Àwọn oun tí aò kọbiarasí gan ni àwọn oun mèremère yìí gangan, irú “ẹ̀mí” tí àwọn ìbòjú, ère gbígbẹ́, àti iṣẹ́ ọnà yìí lè ní nínú, irú ipò pàtàkì wo ni wọ́n wà yàtọ̀ sí oun tí a le fojú rí lára oun mèremère ọnà náà. Fún àwọn olùwòran, ìjíròrò nípa irú oun mèremère ọlọ́jọ́ orí gbọọrọ gbọdọ̀ jẹ́ àríyàjiyàn nípa oun àtijọ́. Nínú ọ̀rọ̀ Àìmàsìkò nínú ìjíròrò yìí wàyí, àwọn oun mèremère yìí mọ̀ pé èyí jẹ́ àríyàjiyàn nípa ọjọ́ iwájú. Ṣùgbọ́n báwo l’oun mèremère ṣe rí ọjọ́ iwájú sí? Ní pàtàkì jùlọ, kí ni oun mèremère ọnà lè kọ́ wa nípa ọjọ́ iwájú?


Nípa fífi èrò inú orí onídẹ Ifẹ̀ tó sọnù sí ààrín àríyànjiyàn tó ń lọ lọ́wọ́ nípa àwọn oun mèremère ọnà ní Áfríkà, Àìmàsìkò wò sùùn nípa ọjọ́ ọ̀la Yorùbá àti gbogbo àwọn ohun ìní Áfríkà. Ọjọ́ ọ̀la kìí ṣe kí èèyà yàbàrá kúrò nínu ohun àná nìkan. Ó tún lè jẹ́ oun ìdápadà àtiẹ̀wá, ọ̀nà láti kọ́ àti láti sopọ̀. Àìmàsìkò yẹ àbá irú ọjọ́ ọ̀la yìí wò nípa fífa àwọn òǹkàwé wá sínú ìtàn bí Áfríkà ṣẹ ń bá ayé ṣe, ìtàn tí a sọ láti ìwòsùùn ti orí onídẹ Ifẹ̀ tí a sábà máa ń sopọ̀ mọ́ Leo Frobenius. Nínú ìtàn yìí, Frobenius àti àwọn èèyàn ẹ̀ gangan ni a pàdé láti fọrọ̀ wá lẹ́nu wò. Oun mèremère ọnà yìí, kìí ṣe olùkàwé, ló fẹ́ mọ̀ síi, ni ààyè rẹ ń rúu lójú, ló ń ronú nípa ọjọ́ ọ̀la ẹ̀. 


Àìmàsìkò bèèrè pé ká ronú nípa ọjọ́ iwájú lọ́nà tí kìí sẹ àìṣègbè ṣùgbọ́n tó jẹ́ olóṣẹ̀lú gidi. Àwọn ìdí kan wà (ìmúnisìn jẹ́ ìkan lára wọn) tí ìmọ̀ wa nípa Yorùbá fi ǹ jórẹ̀yìn tó sì wà nípò àìmọ̀, bí a ṣe ń fi ara wa sínú ọjọ́ iwájú ilẹ̀ àjèjì òyìnbó. Àwọn ọmọ Yorùbá, bíi àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn, ti bẹ̀rẹ̀ sí ń fẹ́ “mọ” bí ọjọ́ ọ̀la á ṣe rí. Àwọn àṣà ilẹ̀ òyìnbó náà ti wá ń dàbí nǹkankannáà pẹ̀lú oun tó dájú. Àwọn oun èlò ẹ̀rọ tẹkinọ́lọ́jì tí a ń lò, àwọn ìhùwàsí àṣà wa, àti àwọn ilé iṣẹ́ wa, kódà àwọn ìpínlẹ̀ wa àti bí a ṣe ń ronú nípa ìgbà àti àkókò ni a ti kọrí ẹ̀ sí ìlú òyìnbó kí á baà le mú ọjọ́ ọ̀la wa dàbí oun tó dájú. Àwọn oun mèremère ọnà wa rán wa létí pé oun tí ìmúnisìn jẹ́ gangan ni fífi irú ìmọ̀dandan lé wa lórí, nípa fífipámú èyí tó lágídí; iṣẹ́ ìmúnidúrósójúkan, fífàlà láti dábàá pé lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan ìmọ̀ àwọn òyìnbó nípa Áfríkà dájú, àti pé lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji ìmọ̀ àwa ọmọ Áfríkà kò tó nǹkan. Nínú Àìmàsìkò, àwọn oun mèremère ọnà wa ń bèèrè lọ́wọ́ wa nìgbàyẹn láti ṣàyẹ̀wò oun tí a máa sọnù gẹ́gẹ́ bí ọmọ Yorùbá níbi wíwá oun ìdánilójú káàkiri; nínú àìkọbiarasí wa fún oun tí a rò pé kò dájú; nínú ìbẹ̀rùbojo wa fún oun tí a rò pè ó ṣe àìmọ̀.


Ìbéèrè tí Àìmàsìkò bèèrè nígbàyẹn ni pé ọjọ́ iwájú tani a ń níran ẹ̀ nìgbà tí a bá ń jíròrò nípa àwọn oun mèremère ọnà Áfríkà? Àríyànjiyàn ọ̀hún rí bíi pé ó dá ara ẹ̀ lójú lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì ṣùgbọ́n nínú Àìmàsìkò ó dàbí ẹni pé kìí ṣe gbogbo apá ẹ̀ ni a ti foju wò dáadáa. Ti àwọn oun mèremère ọnà fúnra wọn gaan ńkọ́? Kíni àwọn máa fẹ́? Níbí yìí, a ní láti bèèrè ìbéèrè nípa ipò ilé ìkóun mèremère ọnà sí. Kìí ṣe nítorí àríyànjiyàn yìí nìkan ṣùgbọ́n nínú ọjọ́ iwájú Yorùbá àti gbogbo ilẹ̀ Afríkà. Ǹjẹ́ ilé ìkóun mèremère ọnà sí lè tẹ̀síwájú ju ipò tó wà nísìsinyìí gẹ́gẹ́ bí ilẹ́ ìpamọ iṣẹ́ amúnisìn òyìnbó bi? Ǹjẹ́ mùsíọ́mù sí lè ṣe ìdápadà bí? Ní pàtàkì jùlọ, kíni ó tún wà lẹ́yìn mùsíọ́mù? Àwọn oun mèremère ọnà wa jẹ́ oun alààyè tó ń bèèrè ìbéèrè nípa oun tí a gbà pé ó ṣe pàtàkì láti mọ̀. Àìmàsìkò pè wá láti ṣe àyẹ̀wò ọjọ́ ọ̀la gẹ́gẹ́ bí ipa tí a fi ń jáde kúrò nínú oun tí a mọ̀, láti dìmọ́ àti láti tún ara wa rí nínú oun àìmọ̀.


Wálé Lawal

Padà sí ojú ewé ti tẹ́lẹ̀