Àdìrẹ

Àdìrẹ ṣì wà láàyè dáadáa. Awọn tí wọ́n ń pa aṣọ ní aró àti àwọn tí wọ́n ń ya bátáni sí ara aṣọ ní Ilú Abẹ́òkúta kò fi ìgbà kankan dáwọ́ iṣẹ́ dúró lórí iṣẹ́ ìlọsíwájú àti ìdàgbàsóké Àdìrẹ̀ yìí ní ṣíṣe.

©Adolphus Opara
©Adolphus Opara
©Adolphus Opara

Àwọn tí wọ́n ń ṣe àwọn àdìrẹ̀ wọnyí ti mú àwọn àṣà àti àrà òde òní tí ó jẹ́ mọ́ aláwọ̀ kàlánkìní àti ìlò àwọn àrà àbẹ́là lára aṣọ wọ inú àrà iṣẹ wọn. ìgbéjáde iṣẹ́ tuntun tí ó tún ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde ni ìlò screen printing àti àrà ‘spatter’. Tọkùnrintobìnrin ni wọ́n ti ń kópa nínú iṣẹ́ àdìrẹ ṣíṣe ní òde òní, ṣùgbọ́n àwọn obìnrin ni wọ́n ṣi pọ̀jù ní ìdí òwò Àdìrẹ. Ìwàjú ní Àdìrẹ wà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àṣà oge ṣíṣe. Àwọn adáṣọlárà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ń ṣe àfihàn àdìrẹ ní àwọn ìpàtẹ̀ ìṣàfihàn àṣà káàiri gbogbo àgbáyé.

©Adolphus Opara
©Adolphus Opara
©Adolphus Opara