Fẹlá Kútì

Fẹlá Aníkúlápó-Kútì jẹ́ akọrin kan láti Nàìjíríyà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin ẹ̀ nípa kíkọ ìdàpọ̀ highlife àti àwọn orin ìbílẹ̀ fún ìgbádùn àwọn olólùfẹ́ ẹ̀.

©Aderemi Adegbite
©Aderemi Adegbite
©Aderemi Adegbite

Nígbà tó ń kẹ́kọ̀ọ́ orin ẹ̀ ní Lọ́ndọ́nù, ó ṣeré pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ẹ̀ tí a ń pè ní Koola Lobitos (1963–1969), kó tó padà sí Nàìjíríyà láti bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò mìíràn. Ó kọ́kọ́ gbìyànjú pẹ̀lú jazz, highlife, afro-soul àti orin ìbílẹ̀, èyí tó wá yípadà di ẹ̀ka orin tó ń pè ní Afrobeat tí a fi wá mọ̀ọ́ lọ́ba káàkiri àgbáyé. Fẹlá máa ń kọrin fún ọpọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ ẹ̀ káàkiri àgbáyé. Ìkan lára àwọn atọ́kùn iṣẹ́ ní Gbọ̀ngàn J. Randle kàn sí àwọn ẹbí Fẹlá Aníkúlápó-Kútì láti yá díẹ̀ lò lára àwọn nǹkan láti inú ilé ìrántí ẹ̀, Kalakuta Museum; bàtà ẹ̀ méjì àti aṣọ tó ní iṣẹ́ ọnà ilẹ̀ Íjíbítì àtijọ́ tí ó dúró fún ẹ̀rí ọkàn ni a gbà láti yálò.

©Aderemi Adegbite