Josy Ajiboye

Josy Ajiboye (oníṣẹ́-ọnà àti aya kàtúnnù), ó ṣiṣẹ́ ní ilé ìwé ìròyìn Daily Times gẹ́gẹ́ bíi a fi kàtúnùnnù sọ̀tàn láti ọdún 1971 sí ọdún 2000. Àwọn Kàtúnùnnù rẹ̀ jẹ́ afàwùjọ ṣẹ̀fẹ̀ torí wọn máa ń dá lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ Nàìjíríà ní àsìkò tí epò rọ̀bì dé sí orílẹ̀ èdè náà. Ní ìgbà yìí ni Kàtúnùnnù rẹ̀ “Josy Ajiboye on Sunday” gbajúmọ̀.

©Adolphus Opara
©Adolphus Opara
©Adolphus Opara

Yíya àwọ̀rán láti ara àwọn ìtàn tí ó gbajúmọ̀, ó yà nípa ìwà ọ̀daràn, kíkùnà ìjọba Nàìjíríà láti pèsè àwọn ohun amáyedẹrùn bíi iná, ọ̀nà tí ó dára, àti omi fún àwọn ará ìlú, bí o ti jẹ́ wípé epò rọ̀bì mú ìlú náà lọ́rọ̀ síi. Alámojútó fún Gbọ̀ngàn John Randle ṣe àbẹ̀wò sí Ajiboye ní Oṣù Ògún, ọdún 2020, tí ó sì rí àká ìpamọ́ kàtúnùnnù rẹ̀ pẹ̀lú ojúlówó àwọn tí ó lò fún àtẹ̀jáde iṣẹ́ ọnà rẹ̀ nínú “ Sunday Times cartoon strip” – èyí ṣe iyebíye púpọ̀.

©Adolphus Opara
©Adolphus Opara
©Adolphus Opara