Ìgbékalẹ̀ Ibi Ìṣàfihàn Títíláí (Ìtẹ̀síwájú)

Àṣà Yorùbá jẹ́ ìkan lára àwọn àṣà tó tóbi jù lágbàáyé, tí ó ṣe agbátẹrù ẹ̀sìn, oun àkọsílẹ̀, orin, àti àṣà iṣẹ́ ọnà ńláńlàa. Ìfẹ́ inú Gbọ̀ngàn John Randle ni láti tanná sí àwọn àṣà àti ìṣe àtijọ́ yìí. Àṣà Yorùbá ò dúró s’ójú kan. Ọ̀rọ̀ Yorùbá tí a pè ní Àṣà ǹ sọ nípa títúnṣe, yíyọdànù àti mímudọ̀tun. Àṣà Yorùbá ń yípadà ní gbogbo ìgbà láti fún wa ní ìmọ̀ràn fún ibi tí a wà àti ọjọ́ iwájú. Ọ̀rọ̀ ìṣe “pa” sí ṣíṣẹ́dánǹkan, mímú nǹkan papọ̀. Pípa àálọ́ (Pa Ìtàn) jẹ́ láti wọ inú àwọn àṣà àti ìṣe yìí. Gbọ̀ngàn John Randle Centre darapọ̀ mọ́ àṣà àti ìṣe àtẹ̀yìnwá pẹ̀lú tòní, a sì tẹjú mọ́ ọjọ́ iwájú.    


Ìsọ̀yè wa fún Gbọ̀ngàn John Randle yìí ni ìwé kan láti ọwọ́ Rowland Abíọ́dún tí a pè ní Yoruba Art and Language. Bi Abíọ́dún ṣe rí àṣà Yorùbá sí jẹ́ ìrànwọ́ fún ṣíṣe àfihàn yìí, pẹ̀lú àfikún iyebíye láti owó àwọn olúbáṣiṣẹ́ Jacob Olúpọ̀nà, Henry Drewal àti Will Rea. 


Kò sí ìtàn ẹyọ kan ṣoṣo tó le kó gbogbo Yorùbá já. Eléyìí jẹ́ tiwa. Ìwọ náà á ní tìẹ. A ò ṣètò ìtàn àwùjọ àti ìdàgbàsókè Yorùbá tó mọ́ tóní látìbẹ̀rẹ̀ dópin. Dípò èyí, a ṣètò àfihàn yìí láti láti mú ẹ rìnà láti ìgbà àìmọ̀ àti ìtàn sí àsìkò ìgbàlódé àti sí ọjọ́ iwájú tí a lérò. Bí a ṣe ń ṣe èyí, a lérò láti ṣàfihàn àwọn àṣà tí a dámọ̀ àti àwọn tó lè ṣe ni ní kàyéfì. Ìṣàfihàn yìí, nítorí pé ó jẹ́ ìṣàfihàn, ní láti ṣe oríṣiríṣi ìpinnu; ó jẹ́ ọ̀nà wa láti ṣàfihàn ìtàn ni. Papàá jùlọ, a lérò pé á mú ẹ ronú nípa ìtàn tìẹ, àti pé wàá lérò láti sọ fún wa nípa ẹ̀. A fẹ́ gbọ́ ìtan tìẹ.     


Àwọn èèyàn tán pe ara wọn ní Yorùbá jẹ́ ìkan lára awọn àpapọ̀ ẹ̀yà tó tóbi jù l’Áfrikà. Èdè Yorùbá ni bíi ọgbọ̀n mílíọ́nù ènìyàn ní Nàìjíríyà ń sọ, a sì tún ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn lágbàáyé tó ń sọọ́. Ìtàn Yorùbá yìí jẹ́ ìtàn oun àti àwọn ènìyàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí a hun pọ̀. Látijọ́, jíjẹ́ Yorùbá jáde láti inú àwọn ìjọba kékèké tí wọ́n farapẹ́ra (nínú àwọn ìlú bíi Ifẹ̀ àti Ọ̀yọ́) tí wọ́n tìtorí ogun, ìkóniẹ́rú (tó tún jẹmọ́ ti Ìlú Ọba) àti òṣèlú bẹ̀rẹ̀ sí lo ìfarajọ àṣà àti ìṣe láti pera wọn ní ìkannáà. Àṣà ìní Yorùbá ni a dá lé orí ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé níbi tí Olódùmarè ti dá ayé sí Ilé Ifẹ̀, tí ó gbòòrò láàárín 1100 àti 1700. Àwọn ìlú yìí ṣì wà ní àárín ìgbàgbọ́ àti ẹ̀sìn Yorùbá, lórí àwọn òrìṣà tí wọ́n ń sìn (bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yorùbá nísìnsìnyí ni wọ́n ń pe ara wọn ní Ẹlẹ́sìn Ìgbàgbọ́ tàbí Mùsùlùmí). 


Púpọ̀ nínú àwọn ìlú Yorùbá ni wọ́n sọ pé ìpìlẹ̀ wọn wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ọkùnrin tí ọba Ifẹ̀ kìnní — Odùduwà — bí. Láàárín sẹ́ntúrì 17th àti 19th, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìlú yìí ni wọ́n ri ara wọn bọ inú ìjọba Yorùbá ìlú Ọ̀yọ́. Ọ̀yọ́ jẹ gàba nípa àṣà fún ìgbà pípẹ́ kí àwọn ìjọba Fúlàní ìlú àríwá tó paárun ní bíi sẹ́ntúrì 19th. Sẹ́ntúrì 19th jẹ́ ìgbà hílàhílo; Ọ̀yọ́ tún agbára ẹ̀ mú nílú Ìbàdàn, ó sì gbìyànjú láti borí gbogbo gúsù ìwọ̀-òòrùn Nàìjìríyà. Ní 1898, ìjagunborí Ìlú Èkó láti ọwọ́ ìjọba Ìlú Ọba òyìnbó ni ó fààyè gba àlàáfíà ní gbogbo gúsù ìwò-oòrùn Nàìjíríyà. Sẹ́ntúrì 20th ni a ti rí ìṣọ̀kan Yorùbá àti ìwọlé ẹ̀ sínú orílẹ̀ èdè Nigeria.


Fún Abíọ́dún àti àwọn akẹgbẹ́ ẹ̀, àṣà Yorùbá tẹ̀síwájú láti gòkè àgbà àti láti tẹ̀síwájú. Nítorínáà, ìṣàfihàn yìí jẹ́ oní ṣíṣí sílẹ̀. Àwọn àlejò ọmọ Yorùbá le lọ sínú ibi ìfarapamọ́-sọ̀rọ̀ láti sọ oun tí àwọn rò pé àṣà Yorùbá le nílò láti tẹ̀síwájú. Fún àwọn oníṣẹ́ ọnà, ìpèníjà wọn ni láti sọ oun púpọ̀ nínú ààyè kékeré. Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n nílò láti ṣẹ̀dá ààyè láti fi ìṣe àti àṣà ilẹ̀ Yorùbá kan hàn; tí wọn á sì fi ìṣe àti iṣẹ́ ọnà gbajúgbajà ojojúmọ́ wọn hàn. Ìpèníjà kejì ni láti mú àwọn ohun yìí wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àṣeyọrí ọmọ Yorùbá kọ̀ọ̀kan nínú ayé òde òní àti láti wo bí àṣà Yorùbá àti àwọn tó ń pe ara wọn ní Yorùbá ṣe máa fi sẹ́ntúrì 21st dábírà.

Padà sí ojú ewé ti tẹ́lẹ̀