Adé Ìlẹ̀kẹ̀

Adé onílẹ̀kẹ̀ àti alaṣọ jẹ́ èyí tí àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n ní èrih pé wọ́n tan mọ Odùduwà, tí ó jẹ́ olùdásílẹ̀ àt Ọba àkọ́kọ́ fún àwọn ọmọ Yorùbá máa ń dé. Òrìṣà ni a ń pe Adé, Òrìṣà tí ìrànṣẹ́bìnrin tí a ṣàyàn máa a ń gbé lé ọba lórí ni. Àwọn òògùn tí ó lágbára ní wọ́n máa ń gbé kó adé náà lórí, láti dáàbò bo orí Ọba àti ọjọ́ iwájú rẹ̀. Ìbòjú tí ó máa ń bo ọba lójú, wà fún ìdáàbòbò irúfẹ́ ẹni tí Ọba jẹ́, a sì tún máa mú kí gbogbo ojú wà lára adé, èyí tí ́ jẹ́ ó jẹ́ orírun agbára. Ẹyẹ tí wọ́n fi ṣẹ adé lọ́jọ̀ dúró fún ẹyẹ oyè tíí ṣe ọ̀kín.

Adé tún le è sọ ìtàn. Adé yìí ní pàtó ṣe pàtàkì púpọ. Ó dúró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí, sí ìtàn èdèàìyedè tí ó wáyé láàárín àwọn Ọba Ẹ̀pẹ́, àwọn olórí Ọba ilẹ̀ Yorùbá àti ṣáà àwọn òyìnbó Amúnisìn. Nínú Adé kan yìí ní pàtó ni ìtàn àjọṣepọ̀ àti òṣèlú sódo sí. 

Ìlú kan ní ìpínlẹ̀ Èkó ni Ẹ̀pẹ́ jẹ́. Ìtan bí a ṣe tẹ ìlú yìí do, jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn ìtàn tí ó ń sọ nípa agbára òṣèlú ní ìpínlẹ̀ Èkó àti àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn òyìnbó amúnisìn. Ó di ilé e Kòsọ́kọ́ nínú ìgbèkùn. Àwọn òyìnbó amúnisìn gba ìjọba lọ́wọ́ Ọba Kòsọ́kọ́, tí í ṣe ọba ìlú Èkó ní ọdún 1851. Àwọn òyìnbó amúnisìn wọ̀nyí fi Ọba Akítóyè jẹ́ Ọba Èkó ní ìgbàtí Kòsọ́kọ sí fi orí oyè sílẹ̀ lọ sí ìlú Ẹ̀pẹ́, ní ibi tí ó ti ó ti fi ara rẹ jẹ ọba pẹ̀lú àṣẹ láti ọwọ́ Awùjalẹ̀ ti Ìjẹ̀bú. Ó padà fí ọwọ́ sí ìwé ìbánigbé-alàáfíà pẹ̀lú àwọn òyìnbó amúnisìn pẹ̀lú ìlérí pé òun kò ní dàmú ìlú Èkó  tàbí kópa nínú oko òwò ẹ̀rú. 

Ẹ̀pẹ́ di ibùdó ìdókowo pàtàkì, tí ó sì ń kópà nínú ìbáṣepọ̀ ìlú Èkó àti Ìjẹ̀bú. Ó ṣe pàtàkì dé ibi wípé àwọn òyìnbó Amúnisìn kò fi ìgbà Kankan gbé ojú kúrò ní ara gbogbo ìgbòkègbodò ìlú náà. 

Ní ọdún 1903, ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàárin Oyèbàjò àti Àkárìgbò ti Ṣàgámù àti Ẹlẹ́pẹ. Akárìgbò fi ẹ̀sùn kan Ẹlẹ́pẹ pé ó wọ Adé onílẹ̀kẹ̀, èyí tí ó jẹ́ Adé tí ó tọ́ sí àwọn ọmọ Odùduwà. Ẹ̀sùn yìí ni ó wáyé látàrí àtúnṣe tí ó wáyé ní ẹkùn Ìjẹ̀bú - ẹ̀yí ti àwọn àwọn òyìnbó Amúnisìn sọ Ẹ̀pẹ́ di Ẹ̀ká rẹ̀. Gómínà ìpínlẹ̀ Èkó ní àbẹ́ ìjọba àwọn òyìnbó Amúnisìn, tíí ṣe Sir William Macgregor, pinnu pé kí Ọọ̀ni Ilé Ifẹ̀ dá ẹjọ́ náà. Ìpinnu Macgregor láti ṣe àgbékalẹ̀ a Central Native Council tí ó jẹ́ ìgbìmọ̀ àwọn lọ́balọ́ba bí àwọn Òyìnbó àti awọn alákọ̀wé ìlú Èkó nínú. Ẹjọ́ yìí jọ bíi pé o fara pẹ́ èrò rẹ̀ – Ìṣàmúlò òfin ìṣèjọba tí a mọ̀ sí indirect rule. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ atótónu, Ọọ̀ni fi sọ pé, Adé Ẹ̀pẹ̀ kò ti ilé Ifẹ̀ ṣẹ̀ wá. Lọ́rọ̀ kan, kò sí ìlọ́wọ́sí àṣẹ Odùduwà lára rẹ̀. Báyìí ni Macgregor ni kí Ẹlẹ́pẹ san owó ìtanràn Ọgọ́rùn un dọ́là, tí wọn sì tún gbé ẹsẹ̀ lé àwọn nǹkan bíi Adé àti bàtà onílẹ̀kẹ̀ ti ìlú Ẹ̀pẹ́ yìí. Àwọn nǹkan wọ̀nyí di èyí tí wọ́n kó lọ sí British Museum, ní ibi tí wọ́n wà di àkókò yìí.

Adé onílẹ̀kẹ̀ tí Ẹlẹ́pẹ ti padà dé sí ìlú Èkó, Ẹ̀pẹ́ sì ti ìlú tí wọ́n ti ń dé Adé onílẹ̀kẹ̀ báyìí.

©The Trustees of the British Museum
©The Trustees of the British Museum
©The Trustees of the British Museum
©The Trustees of the British Museum