Bátánì tí ó máa ń wà lára àdìrẹ jẹ́ èyí tí wọ́n dìídì ṣe sí ara rẹ̀ kí ó tó di wípé wọ́n rẹ ẹ́. Ọ̀nà méjì pàtàkì ni ó wà. Àdìrẹ oníko, tí wọ́n máa ń lo Raffia fún tàbí kí wọn rán an. Nínú kí wọ́n fi nǹkan sí inú aṣo tí wọ́n dì (Àdìrẹ Eléso) tàbí kí wọ́n di aṣọ náà kí ó le, kí aró mà sì lè de àwọn ibi tí wọn bá di (Adire Ẹlẹlọ).. Irúfẹ́ ìlànà yìí ni ó so mọ èyí tí wọn máa ń rán. Wọn a di aṣọ náà, wọn a sì rán an láti dá àrà sí ara rẹ̀ kí ó lè ní bátánì (Ẹlẹ́sun). Àdìrẹ Ẹlẹ́kọ ní wọn máa n fi sítáàṣì sí. Ó ṣé ṣekí ó jẹ́ pé ọdún 1910 ní èyí bẹ̀rẹ̀. Ọ̀nà méjì ní Ẹlẹ́kọ, nínú kí wọ́n fi ọwọ́ dárà síi lára tàbí kí wọn lo páli, iké tàbí irin. Èyí tí wọn fi ọwọ́ dára sí ní o máa ń wá láti Ìbàdàn jùlọ, ṣùgbọn èyí tí wọn máa ń lo ike, irin tàbí páli fún jẹ́ èyí tí àwọn Abẹ́òkúta gbájúmọ́ jùlọ ní ṣíṣe.
Aṣọ èyí tí wọn máa ń lo ike, irin tàbí páli yìí ni a mọ̀ sí Ọlọ́ba (ní èyí tí ó túnmọ̀ sí oní-ọba). Bákan náà ni wọn tún máa ń pè é ní Jubilee. Àwọn àwòrán tí ó wọ́pọ̀ lára rẹ̀ ni Ọba Birítíìṣì (King George V) àti Olorì (Queen Mary). Aseyẹ àyọ́jọ odún márùndínlọ́gbọn wọn ní ọdún (1935) ni wọn ṣe jákèjádò gbogbo Ìlú British pẹ̀lú oríṣ̀ìíríṣìí nǹkan tí ó ní àwòrán ọba àti Olorì nínú gbàgàdà. Àwọn tí wọn sẹ àdìrẹ ní Abẹ́òkúta rí èyí, wọn sì ro wípé àmì aṣọ ńlá ni èyi. Àwọn àwòrán mìíràn ni ó wà lára aṣọ yìí, bíi Ẹṣiń oní ìyẹ́ (Al Baraq) tí ó gbé Mohammed lọ sí Mecca. Àwọn ohun tí wọn kọ yìí ń sọ bí ẹni tí ó wọ̀ ọ́ ṣe tó ní àwùjọ.