Dada Areogun

A bí Agbẹ́gilére Àrẹògún ní ọdún 1880 ní abúlé  Osí-Ìlọrin. Osí àti àwọn abúlé tí ó yíi ká ní agbègbè Èkìtì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ Agbẹ́gilére jàǹkànjàǹkàn ní Áfíríkà tí gbogbo àgbáyé mọ̀ ká. Àwọn òyìnbó British  ra ìlẹ̀kùn yìí láti ṣe àfihàn iṣẹ́ ọnà ọmọ Nàìjíríà ní ibi ìṣàfihàn iṣẹ́-ọnà tí ó wáyé ní ọdún 1924. Ìlẹ̀kùn yìí ṣe àfihàn ìṣẹ̀lẹ̀ ojoojúmọ tih ó ṣeéṣe kí Arẹògún là kọjá ní bíi sẹ́ńtúrí ogún. Iṣẹ́ ọnà náà ṣe àfihàn àlàyé lórí ìgbé ayé ọmọ ènìyàn.

Ní àárín ìlẹ̀kùn náà ni a ti rí ọba tí ó jókòó sí orí ìtẹ́ rẹ̀. Olorì rẹ̀ dúró sí ẹ̀yìn r̀ẹ, nbẹ́ẹ̀ sì ní oríṣìíríṣìí àwọn ènìyàn tí wọn wà ní ààfin yíi ká. Afárá mìíràn ṣe àfihàn àwọn jagunjagun tí wọ́n wà ní orí ẹṣin. Èyí ṣeéṣe kí ó jẹ́ ohun tí Àrẹ̀ògún gbọ́njú mọ̀ nígbà tí ó ń dàgbà ní nǹkan bíi ṣẹ́ńtúrí kọkàndílógún, tí àwọn ìbàdàn kó ogun wá já àwọn agbègbè náà. Ìṣàfihàn ìse ojoojúmọ́: ọdẹ tó ń ti oko ọdẹ bọ̀; obìnrin tí wọ́n mú – bóý ó ṣe aṣemáṣe ní ọjà; àwòrò Ọbàtálá tó ń wúre fún ìyá àti ọmọ tuntun.

Àrẹògún kò ṣàì mọ̀ nípa àwọn àyípadà tí ó ń ṣẹ̀lẹ̀ ní sàkání rẹ̀. Ní ọdún 1898, ìjọba British pàṣẹ kí ogun Kírìjí ó dáwọ́dúró, wọ́n sì ṣe àgbékalẹ ìṣèjọba wọn sí ìlú Èkó. Àwọn Ajẹ́lẹ̀ ìjọba British ṣe àbẹ̀wò sí àwọn ìlú kékèké wọ̀nyí lórí kẹ̀kẹ́ wọn. Orúkọ tí wọ́n ṣábà máa ń pè wọn ní Akéréle. Àwọn British máa ń wá láti gba owó orí, àwọn ará ìlú sì maa bẹ̀rù wọn. Àrẹògún ṣe àgbékalẹ̀ ìmọ̀sílára yìí gàdàgbà, ó fi ère èṣù, òrìṣà olújúméjì ní ọwọ́ kẹ̀ké àwọ̀rán àwọn amúnisìn tí ó gbẹ́.

©The Trustees of the British Museum
©The Trustees of the British Museum
©The Trustees of the British Museum
©The Trustees of the British Museum
©The Trustees of the British Museum