Ère Ìbejì

Àwọn ìran Yorùbá ni wọn ní ìbí ìbejì tí o pọ̀ jù ní gbogbo ayé. Láti jẹ́ ìbejì, tàbí láti ní ìbejì ní inú ẹbí kan jẹ́ àpẹẹrẹ orí ire. Ìbejì ni wọ́n máa ń pe Ọmọ méjì, bẹ́ẹ̀ sì ni a ní òrìṣà ìbejì.  Ìyá tí ó bí àwọn ìbeji ni wọ́n ń pè ní Ìyá Ìbejì, ẹni tí ó sì nih ipò pàtàkì. Àkọ́bí ni ó ń jẹ́ Táíwò, òun sì ní wọ́n kà sí àbúrò nínú àwọn ọmọ méjèèjì, ọmọ tí wọ́n bí ṣe ìkejì ni Kẹ́hìndé, ẹni tí ó pàṣẹ fún Táíwò láti “wá tọ́ ayé wò” bóyá ó dára. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń sọ pé Kẹ́hìndé ní agídí.

Tí ọ̀kàn nínú àwọn ìbejì yìí, tàbí méjèèjì bá kú, ìyá wọn yóò ní láti tọ Babaláwo lọ, ẹni tí yóò sọ fún un pé kí ó gbẹ́ ère ìbejì. Ère yìí ni à ń pè ní ère ìbejì, ìyá àwọn ìbeji náà a sì tọ́jú wọ́n bí ìgbà tí wọ́n jẹ́ ìkókó, èyí ni láti tú àwọn ọmọ tí ó ti kú lójú kí wọ́n lè padà wá. Yàtò fún pínpinnu bóyá ó yẹ kí ère ìbejì kọ ilà tàbí kò yẹ, èrè náà ò fi nǹkan kan jọ ọmọ. Wọ́n ṣe àfihàn ara tí ó kún fún ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ sì ní àwọn èrè wọ̀nyí ju èrè lásán lọ - fún àwọn ẹbí wọn, àwọn ọmọ náà ṣì wà, wọ́n sì ń bá wọn gbé láti ara àwọn èrè yìí

Látàrí pàtàkì àwọn ìbejì, àti ikú ọmọ-ìkọ́kó tí ó wọ pọ̀, awọn èrè wọ̀nyí pọ̀ lọ jàra. Èyí ti fún awọn onímọ̀ ìtàn iṣẹ́-ọnà láàyè láti le sọ ní pàtó agbègbè kọ̀ọ̀kan àti àwọn àrà iṣẹ́ ọnà wọn pẹ̀lú oníṣẹ́ ọnà kọ̀ọ̀kan. Èṣùbiyi ará Ibara Orile ni Abeokuta ni ó gbé àwọn ìbejì wọ̀nyí ní bíi ọdún 1890.

©Will Rea
©Will Rea
©Will Rea