Oríṣi Àgọ̀ Egúngún tí ó ń jẹ́ Epa

Àgọ̀ ńlá tí a mọ̀ sí Epa tàbí irúfẹ́ Epa jẹ́ eyí tí a mọ̀ mọ àwọn ìran Yorùbá tí wọhn wá láti Èkìtì. Ibi oríṣìíríṣìí ayẹyẹ ní wọ́n ti máa ń gbé eégún yìí láti yẹ́ àwọn babańlá àwọn ìlú kékèké Èkìtì sí. Ilé kọ̀ọ̀kan àti ìran kọ̀ọ̀kan lè ní ẹ̀kú/àgọ̀, ní èyí wọn wọ́n a gbé jáde láti jùmọ sẹ̀yẹ pọ pẹ̀lú àwọn ẹbí ìyókù nínú ìlú, tí wọn a sì ṣe ayẹ́sí ìlú ní ìṣọ̀kan. Àwọn tí wọn tẹ ilẹ̀ náà dó yìí ni wọ́n máa ń pè ní Imọ̀lẹ̀. Orukọ́ àwọn alálẹ̀ wọ̀nyí le è wà ní oríṣìíríṣìí kí ó sì yàtọ sí ara wọn, ṣùgbọ́n èyí tí ó wọ́pọ̀ tí wọn sì mọ̀ jùlọ ni Epa tàbí Elefon.

Oríṣi Àgọ̀ Egúngún tí ó ń jẹ́ Epa yìí ni irúfẹ àgọ̀ tí ó tóbi jù ní ilẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n gbé láti ara igi kan ṣoṣo. ọ̀nà méjì ni àgọ̀ náà pín sí. Àgọ tí ó bo ojú ni wọ́n mọ bíi odó tàbí ìkòkò, bẹ́ẹ̀ sì ní ó ní ojú ní iwájú tí ọkan sì ń wo ẹ̀yìn. Ní òkè àgọ́ náà, wọn gbẹ́ ère kan tí ó wọ́pọ̀ tí ó bo ojú àgọ̀ náà. Àgọ̀ yìí súró fún ọ̀kan nínú oríṣìí mẹ́tà; akọní tí wọn gbéró, ìyá pẹ̀lú àwọn ọmọ àti olùwòsàn. Àkànṣe èrè yìí lè tọ́ka sí ipò ìtàn Èkìtì ní ìgbà tí ogun àti owò ẹrú ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú jẹ́.   

Sẹ́ńtúrì kọkàndínlógún ni wọ́n gbẹ́ Àgọ̀ yìí ní ìlú Ìlá Ọ̀ràngún. Gbígbẹ́ rẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ tí ó dára láti ṣe àfihàn ara èrè gbígbẹ́ àwọn ìran Olówóníyì, ní èyí tí ó ṣe é ṣe kí ó jẹ́ Agbẹ́gilére Baagunjoko ni ó gbẹ́ ní bíi ọdún 1800 si ọdún 1870 tàbí Fakẹ́yẹ Akobi Ogun ní ọdún 1870 sí ọdún 1946, ẹni tí ó jẹ́ bàbá-bàbá ìlúmọ̀ká agbẹ́gilére Làmídì Fákẹ́yẹ.

©Will Rea
©Will Rea
©Will Rea
©Will Rea