Twins Seven Seven

Oníṣẹ́ onà Táíwò Ọláníyì Ọ̀ṣuntókí (3 May 1944 – 16 June 2011) ni a mọ̀ káàkiri gẹ́gẹ́ bí Twins Seven Seven. Òun ni ó jọ pé ó jẹ́ oníṣẹ́ ọnà tó ga jùlọ nínú àwọn oníṣẹ́ ọnà M̀bárí M̀báyọ̀, tí Jimoh Buraimoh àti Aṣírù Ọlátúndé jẹ ara ẹ̀. 

Twins ò kọ́ṣẹ́ ọnà nílé ìwé. Dípò èyí, ìpàdé ẹ̀ pẹ̀lú òjọ̀gbọ́n ilẹ̀ Jámánì Ulli Beier àti ìyàwó ẹ̀ Susanne Wenger ní Òṣogbo ni ó darí ẹ̀ sí iṣẹ́ ọnà. Ní àwọn ọdún 1960 Beier ń ṣiṣẹ́ fún Yunifásitì Ìbàdàn ní ẹ̀ka àwọn tí kìí ṣe òṣìṣẹ́ gbòógì (extra-mural department). Ó dá ilé ìgbafẹ́ kan sílẹ̀ l’Óṣogbo tí ó farajọ gbajúgbajà Mbari club ti Ìbàdàn. Àwọn ààyè orin ní ilé ìgbafẹ́ náà ló kọ́kọ́ fa Twins wá síbẹ̀, ṣùgbọ́n Beier àti Wenger (ìgbà tó yá ìyàwó Beier kejì Georgina) gbàgbọ́ nínú pípèsè àwọn oun èèlò iṣẹ́ ọnà. Eléyìí fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn oníṣẹ́ ọnà láti rí irú oun tí wọ́n fẹ́. Twins sì yí ìfẹ́ rẹ̀ sí iṣẹ́ ọnà àfojúrí ní kíakíá.

Iṣẹ́ ẹ̀ gbà láti ara ìdarapọ̀ ìtàn Yorùbá àti àṣà, àti ìran oníkálukú, tí a gbé kalẹ̀ láti ara iṣẹ́ àtinúdá kọ̀ọ̀kan tó ń lo ìlà tí a dá mọ̀ nínú búlọ́kù, ìtòpọ̀, àti àràm̀barà. Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tó ṣe nígbẹ̀yìn, bíi èyí, ni ó ń lo agolo aláfọwọ́kàn, tí ó ń fi bí oun tó yà ṣe rí gan hàn. Nígbà púpọ̀, ó máa ń lo àwọn ìtàn tó jọ mọ́ ìlú Òṣogbo; níbíyìí, a rí ọdẹ, tó jẹ́ alálẹ̀ òrìṣà Òṣun, tó ń gbé igbá ẹ̀.

©Adolphus Opara
©Adolphus Opara
©Adolphus Opara