Àpótí àtúnṣe

Àjọṣepọ̀ tí àwọn Òyìnbó aláwọ̀ funfun àti àwọn Yorùbá ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ní sẹ́ńtúrì kẹrìdílógún, bẹ́ẹ̀ni ìtàn fi yé nipé wọn jùmọ̀ ní àjọṣepọ̀ òwò ní ètí òkun. Ìlú Èkó bá di ibùdó Ajẹ́lẹ̀ àwọn Òyìnbó Aláwò funfun ní ọdún 1842, tí wọ́n sì jẹ gàbalé pátápátá ní ọdún 1862. Síbẹ̀, inú Èkó ṣe àjèjì sih àwọn òyìnbó wọ̀nyí, títí tí Clapperton, Park àti Lander fi ṣe àyẹ̀wò/ìfimúfínlẹ̀/ìwádìí rẹ̀. Ojú tí àwọn oyìnbó Yúróòpù fi ń wo orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti àwọn olúgbé inú rẹ̀ tayọ ìlú Èkó ni ó wáyé látàrí àbọ̀ ìwádìí tí àwọn òyìnbó wọ̀nyí ṣe.   Ẹ̀bùn ìjokòó tí Richard Lander gbà wà lára àwọn iṣẹ́ ọnà àkọ́kọ́ tí oh dé United Kingdom láti àárín Nàìjíríà.

A bíi ní Cornwall ní ọdún 1809, Lander sín àwọn òyìnboh afinmúfínlẹ̀ Hugh Clapperton wá sí Nàìjíríà láti fi imúfínlẹ.  Clapperton kú ní ọdún 1837 ní Sókótó, tí Lander tí ó jẹ́ Oyinbó tí ó yè sì pada lọ sí Britenì  láti Kánò tí ìrìnàjò r̀ẹ sì gba àárín Yorùbá kọjá ní ọdún 1828. Ìjọba Birítíṣì sì yan Lander láti lọ wo bí Odò Náíjà ti tó, tí ọmọ ìyá rẹ̀ ọkùnrin tí ó ń jẹ́ John sì báa lọ. Ní àsìkò tí wọ́n ń ṣe ìwádìí yìí wọ́n kó ère oríṣìíríṣìí jọ. Wọ́n sì fi ta Lander lọ́rẹ ní abúlé Borgu tí ó wà ní Kaiama. Ó dá ni lójú wípé Ìjókòó yìí jẹ́ iṣẹ́ ọnà ilẹ̀ Yorùbá bẹ́ẹ̀ sì ni ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ láti Ilú Ọ̀yọ́ ni wọ́n ti ṣe é. Nígbà tí oh ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ọnà ilẹ̀ Yorùbá, Lander kọ wípé, “àwọn ará apá ilẹ̀ Afíríkà yìí, jọ pé wọn ní àwọn ọjìnmí nínú iṣẹ́ ọnà ère gbígbẹ́, ní èyí tí ó jẹ́ iyì fún wọn; bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn iṣẹ́ ọnà wọn kò ṣe e fi wé èyíkéyìí iṣẹ́-ọnà tí mo ti rí ní ilẹ̀ Yúróòpu tí ó fara pẹ́ẹ lójú”. 

Kìí ṣe odidi ni wọn gbẹ́ igi náà bí kò ṣẹ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ní ìpele ní ìpele ni wọ́n gbẹ́ igi náà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n so wọ́n, tí wọ́n sì kan gbogbo wọ́n papọ. Àwọn ìjokòó tí ó fi ara pẹ́ èyí ṣì wà ní agbègbè Meko in Ìwọ̀ oòrùn Yorùbá. Ó ní láti jẹ́ wípé níṣe ni wọ́n dá àeọn ìjokòó wọ̀nyí padà sí Ingiláǹdì lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n si gbé wọn pamọ́ sí Ilé àkójọpọ̀ àwọn ìsúra ìgbàani tí Biritéènì títí di àìpẹ́ yìí.

Kí ni àwọn nǹkn tí kò sí nínú ìtàn Landa? Ní ìdà kejì – ìtàn ilẹ̀ Áfíríkà. Nitorí náà: kí ló dé ti ìjokòó náà wà ní Kiama? Kí ni Ọ̀yọ́ ń ṣe ní àsìkò yìí? Ṣé wọ́n ń wá agbára ipá ni? Lander sọ ̀tàn rẹ̀ bí ìgbà tí ó jẹ́ wípé òun ni ó wà ní àárin gbùngùn ayé, ṣùgbọ́n níṣe ni ó jẹ́ òyìnbó afimúfínlẹ̀ kan lásán, tí ó kàn ń ṣe àṣìṣe kiri ní àwùjọ tí ko ti lè mọ nípa rẹ̀.

Gbọ̀ngàn John Randle ti tún ìtàn yìí gbé yẹ̀wò tí wọ́n sì ti bèèrè fún ijòkó náà pada. Èyí ni ìtàn ẹ̀bùn àti Ìdápadà/ẹ̀san.

©Wellcome Collection
©Wellcome Collection
©The Trustees of the British Museum
©Wellcome Collection