Ní bí òpin ọdún 1940s, wọ́n ṣẹ àfikún ìrinṣẹ́ pàtàkì sí ohùn orín jùjú, òhun náà ni bàtá. Ó jẹ́ ọkan lára àwọn orin ilẹ̀ Yorùbá tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí ó sì ń sojú ìṣe àwọn ará gúúsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà, èyí tí ó sì tí di gbígbé kiri gbogbo àgbáyé. Ìlú olójú méjì yìí jẹ́ oríṣìí máarùn ún ní títobí, ní èyí tí a lè fí ọwọ́ lù tàbí kí a lo ọ̀gọ́ láti lù ú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bàtá jẹ́ ọ̀kan nínú ìṣe ìlú Yorùbá tí ó pẹ́ jùlọ, ìlù náà àti èdè àrà ọ̀tọ̀ rẹ̀ tí wá di ohun àjòjì sí púpọ̀ nínú àwọn ọmọ Yorùbá òde òní.
Bàtá jẹ́ irinṣẹ́ kàn pàtàkì jùlọ nínú ìṣe “Ìlù Yorùbá”. Nítorí pé ó le è “sọ̀rọ̀” nípa ṣíṣe bíi ohùn àti ìwọ́hùn èdè Yorùbá, ìlú náà ṣe àkópọ̀ oríṣìíríṣìí àwọn ohun alohùn Yorùbá bíi òwe àti oríkì orúkọ (àwon kékèké tí wọ́n fi máa ń ṣe àpọ́nlé àwọn ẹni iyì láwùjọ) tí wọ́n máa ń fi bọ inú eré jùjú, ní ọ̀pọ̀ ìgbà tí wọ́n máa ń jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ orin. Lílé àti ègbè (èyí tí ó jẹ́ àdámọ́ ọ̀pọ̀ orin ilẹ̀ adúláwọ̀) wọ́n sì ṣe àfikún jìtá oníná lẹ́yìn bí ọdún díẹ̀, tí ó sì jẹ́ àfikún sí àwọn irinṣẹ́ tí ó wà nílẹ̀ láti ri dájú pé ìdọ́gba tí ó dán mọ́rán wà láàárín ohùn àti àwọn irinṣẹ gẹ́gẹ́ bí ó tí tọ́ nínú orin jùjú.
Ó ti pẹ́ ti “Ìlù dùǹdún” ti ní àwọn ogbóǹtarìgì olórin tí wọn mọ̀ nípa àṣà àti iṣe tí wọ́n sì yááyì. Tí a bá wo ti Àṣà Gúsù ilẹ̀ Adúláwọ̀, kò sí àkọsílẹ̀ èdè. Pàápàaní Nàijíríà ní pàtó, ìlù bàtá dúró gẹ́gẹ́ ọnà ìbánisọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣojú fún èdè orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí a mọ̀ sí Yorùbá, Ó jẹ́ àrokò láàárín àwọn onílù tí ó jẹ́ wí pé kìí ṣe gbogbo ènìyàn ni ó mọ ìtunmọ̀. Ní ìgbà tí ó jẹ́ wípé ìró ìlù le è lọ jìnnà, nínú ìtàn, wọn a máa lo ìlù bàtá láti pàrokò nípa ogun. Ṣùgbọ́n Yorùbá jẹ́ èdè olóhùn tí ó sì máa ń lo ohùn dídùn, bẹ́ẹ̀ ní ìwọ́hùn dùǹdún jọ èyí, nítorí kí gbogbo ẹni tí ó ń sọ èdè Yorùbá le è ní òye ohun tí ìlù ń “sọ”. Àwọn ìlú bíi bàtá wá di ohun tí wọọ́n ń ṣe àmúlò fún orin, ju fún ìbanisọ̀rọ̀ lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé fún Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún sẹ́yìn àwọn ni wọ́n dúró gẹ́gẹ́ ọ̀nà ìbanisọ̀rọ̀ pàtàkì jùlọ ní àwọn abúlé tí ó wà ni Nàìjíríà.
Àtẹnumọ́ tí ó wà lórí ìwọ́hùn àtijọ àti ohùn lílé-òun-ègbè dúró fún bíi sísọ orin jùjú di ti “Áfíríkà-padà” ní èyí tí ó bọ́ sí déédé àsìkò ìdìde àárín-sẹ́ńtúrì tí ìmọ̀sílárẹ tiwa-n-tiwa bẹ̀ẹ̀rẹ̀. Ní àwọn ọdún tí ó yí òmìníra orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ọdún 1960 ká, I.K. Dairo jẹ́ olórin jùjù tí ó gbajúgbajà jùlọ ní orílẹ̀ èdè náà. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe àfikún àwọn ohun kọ̀ọ̀kan sí àkójọ irinṣẹ́ orin náà, Dairó ní pàtàkì jùlọ mú kí orin jùjú sún mọ àṣà Yorùbá, pàtàkì jùlọ nípa ṣiṣe àtẹmọ ìlò ìlù dùǹdún tíí ṣe ti Yorùbá.
Pèlú ẹgbé orin rẹ̀ tí ó ń jẹ́ Morning Star Orchestra, (tí ó pada wá di Blue Spots), Dairo gbé ọ̀pọ̀ àwo orin jáde ní bíi òpin ọdún 1950s sih ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ ọdún 1960s
Àwọn olórin jùjú tuntun tí wọ́n tún jẹ́ alátúdá orin jùjú ni Ebenezer Obey àti King Sunny Ade. Obey ní pàtàkì jùlọ, fi kún iye jìtá tí ó wà nínú irinṣẹ́ orin jùjú, ó fi ìlànà ìwàásù àwọn ọmọlẹ́yìn Krístì kún un, pẹlú àwọn ọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ inú ayé, ní èyí tí ó jẹ́ kí orin rẹ̀ wà ní òkè téńté. Adé ní tirẹ̀, ẹni tí ó ní ọ̀pọ̀ tí oh gbọ́ orin rẹ̀, túbọ̀ fi kún àwọn irinṣẹ́ orin jùjú tí ó sì jẹ́ kí ó ní jìtá bíi márùn ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn alurinmọ́ra tí ó pọ̀ àti atẹdùrù oníná, ní àfikún ni ọ̀pọ̀ àwọn agberin olóhùn dídùn.
Láti bíi òpin 1960s tí àárín 1980s, Obey àti Adé figagbága fún ẹni tí irínṣẹ́ orin jùjú rẹ̀ pọ̀ jù tí ó sì rinlẹ̀ jùlọ. Látàrí èyí, púpọ̀ nínú àwọn ọkọrin jùjú nì́ ilẹ̀ Yorùbá bá ìnànà gbígba oríṣìíríṣìí orin àtọhún-rìn-wá tí ó gbajúgbajà láàyè láti wọ inú àrà orin wọn.