Bísí Fákẹ́yẹ

Bísí Fakẹ́yẹ jẹ́ ìlúmọ̀ká agbẹ́gilére, ó wá láti ìdílé agbégilére tí ó gbajúmọ̀. Bàbá-bàbá-bàbá rẹ̀ ni agbẹ́gilére Ọláwọyin láti Ìlá Ọ̀ràngún. Ìbátan Lamidi Fakeye ni ó jẹ́. Àwọn ẹbí Fákẹ́yẹ ti gbé àwọn ìṣe àdayébá èrè gbígbẹ́ ilẹ̀ Yorùbá ga, wọn sì ti sọ ìṣe náà ti gbajúgba dé òkè òkun.

©Adolphus Opara
©Adolphus Opara
©Adolphus Opara

Ìlú Ìbàdàn ni Bísí Fákẹ́yẹ ń gbé báyìí, ní ibi ti alámójútó John Randle ti ṣe àbẹ̀wò síi. Àwọn ohun èlò ìgbàlódé ni ó ń lò ní ìsìnyí, ṣùgbọn àwọn ìgbéṣẹ iṣẹ́ ọnà rẹ̀ kò lè jẹ́ àjèjì sí bàba-bàbá rẹ̀. Alámójútó John Randle ní kí Bisi Fakeye ṣe àfihàn iṣ́ẹ́ ọnà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ògbọ́ntarìgì agbẹ́gilére. Ní ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́, Ọnà-Líle, èyí ni gígé iṣẹ́ ọnà náà ní pàtó kalẹ̀ – Èyí ni ìgbésẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí ó sì jẹ́ wípẹ́ Oníǹkan gan an tí ó ní àṣẹ́ lórí iṣẹ́ ọnà náà ni ó gbọ́dọ̀ ṣe é. Àwọn ìgbésẹ̀ tí ó kù ni; Alẹ̀túnlẹ̀, Dídán àti Fínfín.

©Adolphus Opara
©Adolphus Opara
©Adolphus Opara