Ebenezer Obey

Ebenezer Obey ni a mọ káàkiri fún irú orin jùjú ẹ̀ tí a mọ̀ sí mìlíkì (“ìgbàdún jẹ́jẹ́”).

©Aderemi Adegbite
©Aderemi Adegbite
©Aderemi Adegbite

Iṣẹ́ orin ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu ní ààrín-1950s l’Ékòó. Látìgbàyíwá, Obey ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ẹ̀ tí a pè ní The International Brothers, tí ó dá sílẹ̀ ní 1964 kó tó di Inter-Reformers Band níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1970. Pẹ̀lú ẹgbẹ́ yìí, ó rìnrìnàjò káàkiri ayé, ó sì gbé oríṣiríṣi àwo jùjú jáde lóri àtẹ West Africa Decca. Ìkan lára àwọn atọ́kùn iṣẹ́ ní Gbọ̀ngàn J. Randle kàn sí Chief Commander Ebenezer Obey nílé wọn ní Ikeja. Wọ́n fìfẹ́ yá wa ní díẹ̀ nínú ìbora àwọn àwo orin wọn láti 70s, 80s àti 90s, àṣọ àti bàtà tí wọ́n wọ̀ fún eré àti orin wọn ní 80s àti 90s, ní Nàìjíríyà àti òkè òkun, jìtá Hawaii kan, àti jìtá àdánìkanta kan fún Gbọ̀ngàn wa.

©Aderemi Adegbite
©Aderemi Adegbite
©Aderemi Adegbite
©Aderemi Adegbite