Lola Shoneyin

Lola Shoneyin (akéwì àti òǹkọ̀wé) jẹ́ ìlúmọ̀ká látàrí ìwé eré onítàn rẹ̀, àkójọpọ̀ ewì rẹ̀ àti awọn iwé lítíréṣọ̀ àwọn ọmọdé rè. Ìwé eré onítàn rẹ̀ tí ó gba àmì ẹ̀yẹ “The Secret Lives of Baba Segi’s Wives,” èyí tí ó kọ́kọ́ tẹ̀ jáde ní ọdún 2010 tí si ti yí sí oríṣìí èdè mẹ́rìnlà, ní èyí tí èdè Faransé, Dọ́ọ̀ṣì, Rọ́ṣía, àti Sipaníìṣì.

©Adolphus Opara
©Adolphus Opara
©Adolphus Opara

Gbogbo àgbáyé ní wọ́n ti mọ̀ ní pa iṣẹ́ rẹ̀ nítorí ó máa ń dá lórí ìwà àwùjọ àti ojúwòyè àwùjọ nípa ìgbéyàwó àti àjọ tí ó ń rí sih ọ̀rọ̀ abo ní Nàìjíríà. Òun ni olùdásílẹ̀ Aké Arts and Book Festival. Alámójútó Gbọ̀ngàn John Randle lọ sí ọ̀dọ̀ Lọlá, ó sì fi tìdùnnútìdùnnú gbà wọ́n láàyè láti rí àká iṣẹ́ ọnà rẹ̀ èyí ní ibi tí ó kó àwọn ojúlówó iṣẹ́ rẹ̀ sí àti àwọn àwòrán ara rẹ̀ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ti túmọ̀ sí èdè mìíràn, ní èyí tí ó yá Gbọ̀ngàn John Randle.

©Adolphus Opara
©Adolphus Opara