Ọjà Òjé

Ọkan lára àwọn ọjà àtijọ́ tí ó sì gbajúmọ̀ jùlọ ní ìlú Ìbàdàn ni Òjé, tí ó wà ní kílómítà kan dín sí ààfin Ọba. Wọn dá ọjà náà sílẹ̀ ní ọdún 1884, ní ìgbà tí Olúyọ̀lé wà ní orí oyè.

©Adolphus Opara
©Adolphus Opara
©Adolphus Opara

Orúkọ rẹ̀, Òjé ni wọn mú láti ara orúkọ ìlú kan tí kò jìnnà sí Ìlọrin, ó ṣe é ṣe kí ó jẹ àjọṣepọ̀ yìí ni ó fa irúfẹ́ nǹkan tí wọ́n ń tà ní ọjà náà, títa aṣọ òkè. Gẹ́gẹ́ ìtàn, àwọn abúlé àti ìlú kékèké tí ó yí Ìlọrin ka ni wọn máa ń hun púpọ̀ nínú gbogbo àwọn àsọ òkè wọ̀nyí, ṣùgbọn ní ìsìnyí, aṣọ híhun ti di ohun tí àwọn ìlu Yorùbá lóríṣìíríṣìí máa ń ṣe. Òje ni ọjà fún aṣọ òke yìí, bẹ́ẹ̀ sì ní àwọn òǹtajà a rin ìrìnàjò ọ̀pọ̀ máìlì lati ra ọ̀pá aṣọ yìí fún títà ní abúlé wọn. Kóda di àkókò yìí láàárin gbogbo káràkátà tí ó ń lọ káàkiri àgbáyé, ọjà òje ṣi jẹ ọjà aṣọ òkè tí ó dáńgájíá jùlọ tí ènìyàn ti le è rí ojúlówó aṣo òkè ní Nàìjíríà.

©Adolphus Opara
©Adolphus Opara
©Adolphus Opara