Òṣogbo

Igbó Ọ̀ṣun Òṣogbo jẹ́ ilé òrìṣà omi tí a mọ̀ sí Ọ̀sun, ó sì tún jẹ́ àpẹẹrẹ kan ṣoṣo tí ó kù nínú àwọn ohun tí wọn fi máa n sọ nípa bí àwọn ìran Yorubá kọ̀ọ̀kan ṣe tẹ̀dó sí ibi tí wọ́n wà.

©Adolphus Opara
©Adolphus Opara
©Adolphus Opara

Ní inú Igbó yìí, ogójì ojúbọ ni ó wà níbẹ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ ère tí wọn mọ láti yẹ Ọ̀ṣun àti àwọn òrìṣà mìíràn nínú ìtan ilẹ̀ Yorùbá sí. Igbó yìí àti gbogbo ère tí oh wà ní inú rẹ ti di “UNESCO World Heritage Site”. Àwọn mìíràn lára àwọn iṣẹ́ ọnà wọ̀nyí jẹ́ èyí tí “New Sacred Art Movement Artists” ti gbé kalẹ̀ láti bí ogún sẹńtúrì sẹ́yìn lábẹ́ àkóso Suzanne Wenger tí ó jẹ́ oníṣẹ́ ọnà ará Australia tí ó di Olùsin Ọ̀ṣun, láti fi ìdí àjọṣẹpọ̀ tí ó wà láàárín àwọn ènìyàn àti àwọn òrìṣa ilẹ̀ Yorùbá. Lára àwọn oníṣẹ́ ọnà “Sacred Art Movement” bíi Kàsálí Àkàngbé, Rábíù Abesu àti àwọn ìyókù ṣì wà ní ayé, wọ́n sì ń tẹ̀síwájú láti tún iṣẹ́ inú igbó náà se lóòrèkóòrè.

©Adolphus Opara
©Adolphus Opara