Irú Ẹ̀kú wo ni o wọ̀ lónìí?

Ní àsìkò àjàkálẹ̀ ààrún yìí, a ti rí i mọ̀ pé a nílò láti wọ ìbòmú láti dáàbò bo ara wa àti àwọn tí wọ́n yí wa ká lọ́wọ́ kòkòrò àìfojúrí. Ní àtijọ́, àwọn ènìyàn kò ní ìmò irú èyí tí a ní yìí. Ṣùgbọ́n ni ìsìnyí gan, ní sẹ́ńtúrì kọkànlélógún, o ti di mímọ̀ káàkiri àgbáyé, pé ọkan lára àwọn ọ̀nà tí ó rọrùn jùlọ láti kọjú àìsàn ni láti wọ ìbòmú. Àwọn ìran Yorùbá ti mọ ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàárín ìbòmú àti ìlera fún ọ̀pọ̀ sẹ́ńtúrì.

Kódà ní òní, rírí ẹni tí ó wọ ẹ̀kú, egúngún, le è mú kí ènìyàn jáyà, kí ó yà ènìyàn lẹ́nù kí ó sì fò ó láyà. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà bí wọ́n ṣe rí a máa mú ènìyàn gbà pé ayé ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti wá – láti ọ̀run, igbó kìjikìji, tàbí àwọn ibi àjèèjì. Ẹgúngún tí ó ń ṣeré jùlọ ní Ìwọ̀ oòrun Nàìjíríà ní a mọ̀ sí Ẹgúngún, àwọn tí wọ́n dúró fún èmí àwọn babańlá tí wọ́n padà wá.  Egúngún gbalẹ̀ púpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú Yorùbá ni wọ́n ti ń gbé egúngún, ṣùgbọ́n tí ẹ̀kú wọn yàtọ̀. Ẹkú ńlá onígi tí a mọ̀ sí Epa, tí wọ́n gbẹ́ àwọn àwòrán jagunjagun, àwọn obìnrin àti oníṣègùn sí òkè ẹ̀kú náà láti ta àwọn ará ìlú jí sí àwọn alálẹ̀ ti wọn pilẹ̀ àwọn ìlú ìlà oòrun, àwọn imọ̀lẹ̀ tí wọ́n ń ṣe àbẹ̀wò sí inú ìlú. Ní apá ìwọ̀ oòrùn, Gẹ̀lẹ̀dẹ́ dé láti bu iyì kún èmí àwọn alágbára obìnrin. Oun tí a kò mọ̀ púpọ̀ ni bí a ṣe máa ń lo ìbòjú láti darí àjàkálẹ̀ àrùn.


Ọkan lárà ìpilẹ̀ ìtàn egúngún ní Ilẹ Èkìtì, tí ó jẹ Ọ̀kan lára ẹ̀ka Yorùbá lọ báyìí…


Ọkùnrin kan ní ààrùn ẹ̀tẹ̀, wọ́n sì lé e kúrò ní oko. Láti rí i dájú pee bi kò pa á, ó pinnu láti máa wọ imọ̀ ọ̀pẹ, tí ó bá ti di ọjọ́ ọjà, yóò fò jáde láti inú igbó, yóó sì lé gbogbo àwọn ọlọ́jàìyá lọ, yóò dẹ́rùbàwọ́n kí wọn le è fi ọjà won sílẹ̀ lọ. báyìí ni ó ń ṣe tí ó sì fi wà lááye. Èyí sú àwọn ìyá ọlọ́jà ní ọjọ́ kan, ṣùgbọ́n kò sí èyíkéyìí nínú wọn tí ó lè do kọ ọ́. Obìnrin kan wà ṣá tí ó pinnu pé kinní náà yẹ ní kíkojú, torí náà, ó wọ inú igbó lọ láti wá a. Ṣùgbọ́n, bí ó ti jẹ́ akínkanjú obìnrin tó, kò ní agbára tó láti gé igbó lulẹ̀, tórí èyí ó ní láti padà sí àárín ìlú láti wá àwọn ọkùnrin tí yóò ràn án lọ́wọ́. Àwọn ọkùnrin méjì tẹ̀lé e wọ inú igbó, ṣùgbọ́n obìnrin náà kò lè tẹ̀lé wọn.  Nígbà tí wọ́n rí egúngún náà wọ́n pinnu pé àwọn fẹ́ràn rẹ̀, torí náà, kàkà kí wọ́n fi han obìnrin náà, wọ́n gbé e pamọ́, wọ́n sì gbé e wá sí inú ìlú. Báyìí ni Owi ṣe dé inú ìlú, torí ìdí èyí ni wọ́n ṣe ń pè é ní egúngún tí ó dàgbà jù.


Èyíkéyìí tí náà ìbá jẹ́, àwọn egúngún a máa dáàbò bo, wọn a sì máa bùkún, àwọn olúgbé ìlú. Ìlera, ọrọ̀ àti àlàáfíà ni wọ́n máa ń so mọ́ àwọn egúngún. Ìlera ni ó dàbí ẹni pé ó ṣe pàtàkì jùlọ, nígbà tí awọn tí ó ṣe pàtàkì jù nínú ìlú sì jẹ́ àwọn ọmọdé. Nínú ìṣẹ̀dá Yorùbá – gẹ́gẹ́ bí egúngún ṣe wá láti ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọdé. Ìgbàgbọ́ yìí ni a le è rí nínú àwọn orúkọ Yorùbá bíi Babátúndé tàbí  Yeyétúndé ní èyí tí ó túnmọ̀ sí àwọn bàbáńlá tàbí ìyáńlá tí ó ti kú ti padà wá. Ọ̀kan nínú àwọn gbólóhùn mìíràn tí ó rọ̀ mọ́ àgọ̀ egúngún ni Ọmọ ọ̀run, ọmọ Aláyé.

©Will Rea
©Will Rea
©Will Rea
©Will Rea