Owó Ẹyọ

Oun tí a ń pè ní owó ẹyọ Cypraea Moneta jẹ́ oun tó wá láti Erékùsù Maldive ní Indian Ocean. Láàárín 1650 àti 1880, ó ju owó ẹyọ bíi bílíọ́nù ọgbọ̀n (30 billion) lọ tí a gbé wá sí Ìwọ̀ Oòrùn Nigeria. Ọkọ̀ oju omi Ilẹ̀ Britain ló kórè wọn, ló gbé wọn lọ síi Lọ́ndọ́nù, tó wá gbé wọn padà sí Ìwọ̀ Oòrùn Áfríkà fún láti ra àwọn ẹrú. 


Ìtàn ìlẹ̀kẹ̀ ní Nigeria gùn gan ni. Kódà lónìí, àwọn iyùn pupa jẹ́ oun tí a fi ń dá àwọn olóyè mọ̀. Lílo ìlẹ́kẹ̀ aláwọ àràmbarà nínú ọ̀ṣọ́ ọba jẹ́ oun tí a ti ń ṣe láti Sẹ́ntúrì Kẹ́tàlá (13th Century). Àwọn ìlẹkẹ̀ Ifẹ̀ jẹ oun tí a ti fi múlẹ̀ pé ó wá láti Ilẹ̀ Yúròpù Àtijọ́ (Murano) àti àwọn Ilẹ̀ Lárúbáwá. Àwọn ará ilẹ̀ Portugal ni wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ra owó ẹyọ wá sí ilẹ̀ wa ní 1515. Kò pẹ́ sí ìgbà yìí ni a bẹ̀rẹ̀ sí lòó gẹ́gẹ́ bí owó. Gbogbo owó irajà yìí wá yípadà nígbà tí Yorùbá wọ inú òwò ẹrú ti Atilántíkì. Nígbà yìí, a bẹ̀rẹ̀ sí lo owó ẹyọ fún ìdána, ìgbéyàwó, àti owó orí.  Ìdúnàádúrà wá di oun àfowóṣe; aò máa ṣe pàṣípààrọ̀ mọ́. Oníkálukú le kó ọrọ̀ jọ nípa owó ẹyọ; nígbà yìí, àwọn olùtajà, tí àwọn obìnrin wà lára wọn, bẹ̀rẹ̀ sí ní mọ̀ọ́kà, wọ́n sì di olówó. Irú ìwà ìfọwọ́araẹniṣiṣẹ́ ti wá bẹ̀rẹ̀. Kò pọn dandan mọ́ pé kí a bí ẹ sí inú ilé ọlá. Pẹ̀lú ọgbọ́n orí àti iṣẹ́ takuntakun rẹ, o lè di ọlọ́rọ̀.


Ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé owó ẹyọ ní ipa pàtàkì lórí àṣà ilẹ̀ Yorùbá. Olókun (to jé “ẹni tó ni òkun Atilántíkì”) wá di ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn Oriṣa wa. Kódà lónìí, òun ni àwọn ènìyàn máa ń bẹ̀ fún ọlá àti ọrọ̀. Bí a ṣe ń bẹ̀rẹ̀ sí gbáralé ara ẹni àti iṣẹ́ ọwọ́ ẹni wá jẹ́ kí a máa gbáralé Orí jùlọ — orí ara ẹni. Nítòótọ̀, Ilé Orí ní Ilé Ifẹ̀ àtijọ́ ni a fi tẹ̀ràkótà ṣe ni gbogbo Sẹ́ntúrì kejìdínlógún, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ilé òrìṣà wọ̀nyí ni a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú owó ẹyọ — tó jé ọ̀nà láti fi ọrọ̀ pamọ̀ àti ọ̀nà láti fi ọlá hàn.  Kódà lónìí, owó ẹ̀yọ jẹ́ ìkan pàtàkì lára oun èlò tí wọ́n máa fi ń ṣe oògùn owó lónìí tàbí lára aṣọ tí a yàn kalẹ̀ fún òrìṣà.


Àwọn oun tó lówó lórí jùlọ tí a rà pẹ̀lú owó eyọ ni ara ọmọnìyàn ní ipò ẹrú. Àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun tó wà ní èbúté ni wọ́n bèèrè fún púpọ̀ ènìyàn síi láti roko ẹrú ní ilẹ̀ Brasílì, ní ilẹ̀ Caribbean, àti ní àwọn ilẹ̀ gúsù Amẹ́ríkà. Wọ́n ní láti san gọboi nínú owó orí ni. Lọ́gán tí àwọn ará Ìlú Ọba ti tẹ̀dó sí èbúté Nigeria, iye àwọn ọmọ Yorùbá tí a gbé kọjá orí òkun Atilántíkì pọ̀ síi.  Láàárín 1780 àti 1850, 1.12 mílíọ́nù ọmọ Yorùbá ni a ti tà s’óko ẹrú. Àwọn ẹrú tó pọ̀jù ló wá sí èbúté láti inú ìgbèríko Yorùbá. Ní ìbẹ̀rẹ̀ Sẹ́ntúrì kejìdínlógún, a máa ń ta àwọn ènìyàn lẹ́rú láti Ọ̀yọ́ gba Òwu àti Ìjẹ̀bú lọ sí Ẹ̀pẹ́ àti Lekki, tàbí láti Ẹ̀gbá lọ sí Ẹ̀gbádò lọ sí Badagry.


Nígbà tó di bíi ìparíi àwọn ọdún 1780, Ọ̀yọ́ ti ń rẹ̀wẹ̀sì, ipa mìíràn sì bẹ̀rè sí ń ṣí ní Ìlà Oòrùn — àwọn èbúté pàtàkì ti wá wà ní Badagry, Èkó, àti Àjàṣẹ́ (Porto Novo). Àwọn òwò yìí wá jẹ́ kí Ilẹ̀ Yorùbá farakó gbogbo rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ nínú òwò ẹrú Atilántíkì àgbàyé yìí. Pónpó irin (bíi Mandelas), ọtí líle, ìbọn àti aṣọ wá di oun ìtajà pàtàkì. Lábẹ́ gbogbo ètò yìí ni owó ẹyọ. 


Ọrọ̀ àti ẹran ara wá di ọ̀kan. Ìtàn àwọn ẹrún tó rì sínu òkun nítorí àti rí owó ẹyọ wá di ohun tí a ń gbọ́ káàkiri (bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ilẹ Maldives nìkan ni àwọn ìlẹ̀kẹ̀ yìí ti máa ń wù). Nǹkan tí a rò nípa ẹran ara àti owó wá di àsopọ̀. Èrò nípa gígé ẹran ara ẹni àti bí a ṣe so èyí pọ̀ mọ́ ìlọ́rọ̀ lè fi yé wa ìburú bí àwọn àhesọ ọ̀rọ̀ ṣe máa ń dìde láàárín wa.

©Will Rea
©Will Rea
©Will Rea
©Philip Henry Gosse